Ìyàlẹ́nu lọrọ náà ṣì ń jẹ fún ọpọ àwọn tó rí gbajugbaja olorin nnì, Yinka Ayefẹlẹ níbi tó ti ń polówó aporo ẹpa Ìjẹ̀bú n'ilu Ibadan lọ́jọ́ Abamẹta, ìyẹn Satide àná.
Yinka Ayefẹlẹ làwọn èèyàn ń káàánú ẹ gidi ẹ nígbà tí wọn rí fọ́nrán rẹ tó gbé sórí ìkànnì ayélujára tí fesibuuku rẹ, níbi tó ti ń polówó Aporo ẹpa Ìjẹ̀bú, tó sì ni ẹnu tí gbẹ kọjá sísọ.
Nínú fọ́nrán náà tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ l'ẹnikan tí béèrè lọ́wọ́ ẹ pé kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi gbegba aporo náà, nibẹ lo tí sọ pé ọ̀nà kan kò wọ ọjà mọ, àti pé òun yóò ṣáá jẹun nígbà tòun kò rí iṣẹ orin gba mọ lásìkò yìí.
Yinka Ayefẹlẹ sọ pé àwọn èèyàn kò pé òun síṣẹ orin mọ lásìkò yìí, òun sì gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà mi-ín láti máa fi rí owó jẹun, ìdí re e tòun fí n sọ fún gbogbo àwọn èèyàn wí pé ìgbà Aporo lòun tún ti gbé báyìí.
Awada lásán ni fọ́nrán tí Yinka Ayefẹlẹ gbé sórí ìkànnì ayélujára rẹ náà jẹ, kí í ṣe pé nnkan ti dàrú fún un. Ọ̀nà láti tún fi dá àwọn olólùfẹ́ rẹ laraya lo fi fọ́nrán náà ṣe.
Inú ọgbà ileeṣẹ redio rẹ, Fresh FM tó wà n'ilu Ibadan, ipinlẹ Ọ̀yọ́ lo tí yà fọ́nrán náà.
Ohun tó dájú ni pé bí Yinka Ayefẹlẹ bá lòun kò ṣíṣẹ orin mọ, ohun ti yoo jẹ́ títí di ọjọ́ alẹ rẹ ni ileeṣẹ redio tó dá sílẹ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tó wà lára àwọn redio tó dára julọ lásìkò yìí torí pé ọ̀nà ìgbàlódé lo fi dá a silẹ, tí kò sì lẹlẹgbẹ.
Ẹ wo fìdí ó náà nibi: Yinka Ayefẹlẹ lórí fesibuuku
No comments:
Post a Comment