ÀWỌN ALMAJIRI TUN YA WỌ ÌPÍNLẸ̀ KWARA L'ỌSAN GANGAN, NI WỌN BA DA WỌ INÚ PADÀ L'ẸNU IBODÈ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 21, 2020

ÀWỌN ALMAJIRI TUN YA WỌ ÌPÍNLẸ̀ KWARA L'ỌSAN GANGAN, NI WỌN BA DA WỌ INÚ PADÀ L'ẸNU IBODÈ


Ọwọ àwọn òṣìṣẹ́ eleto ààbò tún ti tẹ wọn Almajiri mi-ín nipinlẹ Kwara, tí ìgbàgbọ́ sì wá pé ó ṣeé ṣe kí wọn ní àrùn aṣekupani, Koronafairọọsi lára.

Inu igbó là gbọ àwọn Almajiri tí wọn kò dín ni ọgbọn náà gbà láti ipinlẹ Kano tí wọn tí kúrò, títí tí wọn fi dé Kwara, tí a sì tún gbọ pé wọn san owó abẹtẹlẹ lójú ọna láti kọjá. 


Bí wọn ṣe de ẹnu ibodè tó wọ ipinlẹ Kwara ni wọn tún gbìyànjú láti yọ owó síta, kí wọn sì fún àwọn òṣìṣẹ́ eleto ààbò tó wà nibẹ, kí wọn lé rí ààyè kọjá, sugbon ti wọn làwọn yẹn kò gbà á lọ́wọ́ wọn. 

Lójú ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ sì igbakeji Gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi to tún jẹ́ alaga igbimọ àrùn Koronafairọọsi nipinlẹ náà, toun náà sì gbéra láti lọ síbẹ̀ lọ wo wọn. 

Bọọsi bọginni Toyota Hiace elero rẹpẹtẹ là gbọ pé wọn gbé, tí wọn sì san owó rẹpẹtẹ fún awakọ bọọsi náà láti gbé wọn.


Loju ẹsẹ ni igbakeji Gomina tí ni káwọn òṣìṣẹ́ alaabo tí lewaju wọn dé ẹnubodè Kwara sì Niger, èyí tó wà ní Jebba, kí wọn lé dá wọn padà síbi tí wọn tí ń bọ̀. 

Kọmiṣanna ọlọ́pàá ipinlẹ náà, Kayọde Ẹgbẹtokun nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sọ pé Ìbàdàn làwọn èèyàn ń lọ kí àṣírí wọn too tú, àti pé awakọ náà jẹwọ wí pé ṣe làwọn ń san owó láti kọjá làwọn ẹnubodè káàkiri. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI