Ó ṢẸLẸ̀! NÍTORÍ OWÓ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ, GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ PA AYALEGBE ẸGBẸ́ RẸ̀ DANÙ L'ÉKÒÓ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 21, 2020

Ó ṢẸLẸ̀! NÍTORÍ OWÓ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ, GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ PA AYALEGBE ẸGBẸ́ RẸ̀ DANÙ L'ÉKÒÓ


Fíìmù agbalewo l'ọpọ àwọn èèyàn kọ́kọ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọn kò sì fẹ́ẹ kọbi ara sii, ṣùgbọ́n nígbà tí wón rí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe lọ, lo mú kí wọn sáré debẹ. 

Bí kí bàa ṣe ọpẹlọpẹ àwọn ẹlẹyinju àánú àdúgbò ni, ó ṣeé ṣe kí gbajumọ oṣere tíátà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde bọ, Temitayọ Phillips Ogunbusọla tí di èrò ọrun alakeji lórí bí wọn ṣe dawọjọ luu.

Temitayọ ni wọn loo ṣekú pá ọkàn lára àwọn ayalegbe tí wọn jọ ń gbé inú ilé kan náà, nítorí wọn béèrè owó iná tó ti jẹ́ lọ́wọ́ rẹ, tó sì sọ ọ̀rọ̀ náà di wàhálà ńlá.

AWIKONKO gbọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ mọnamọna ni wọn mú ìwé owó iná lọ fún wọn nílé tí Temitayọ ń gbé ní ojúlé kẹrin, àdúgbò Sebil Kazeem tó wà lágbègbè Ṣẹlẹ̀-Igbe, Ikọtun nílùú Èkó lọ́jọ́ Satide ọ̀sẹ̀ to kọjá. 

Bí wọn ṣe de yàrá Temitayọ tí wọn loo tí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọkanlelogun ataabọ {N21,500} náírà lo tí bẹ̀rẹ̀ sii pariwo wí pé kí wọn má de iwájú òun.

Ọladọtun Johnson Ọpẹyẹmi àti Banjọ Lateef là gbọ pé wọn lọ béèrè owó lọ́wọ́ rẹ, ṣùgbọ́n tó lòun kò ní owó kankan láti san, tó sì dá ojú ọ̀rọ̀ náà ru mọ Ọpẹyẹmi lọ́wọ́. 

Níbi tí wọn tí ń fà ọ̀rọ̀ náà là gbọ pé Temitayọ tí lọ fà ọbẹ yọ, tó sì fi gún Ọpẹyẹmi nikun, tí yẹn sì jẹ Ọlọ́run nipe lójú ẹsẹ. 

Báwọn ara àdúgbò ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ni wón ti bẹ̀rẹ̀ sii lu Temitayọ, kò tó di pé wọn ranṣẹ pé àwọn ọlọ́pàá Ikọtun. 

Àwọn ọlọ́pàá ni wọn gbé Temitayọ lọ sí ọsibitu níbi tó ti ń gba itọju lọ́wọ́ báyìí, tí wọn sì ń dúró láti fojú rẹ bá ilé ẹjọ́. 

Agbẹnusọ fáwọn ọlọ́pàá ipinlẹ Eko, Bala Elkana sọ lẹ́yìn tí ara Temitayọ bá ti yà díẹ̀, làwọn yóò fọrọ wáa lẹ́nu wo, kò tó di pé àwọn wọọ lọ síwájú adajọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI