Ẹ JẸ KI N PADÀ SILU MI, NÀÌJÍRÍÀ Ó, GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ BU SẸKUN NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 28, 2020

Ẹ JẸ KI N PADÀ SILU MI, NÀÌJÍRÍÀ Ó, GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ BU SẸKUN NITA GBANGBA


Pupọ àwọn tó rí gbajumọ oṣere tíátà tó tún jẹ́ onkọrin nii, Angela Okorie níbi to tí ń sunkún pé kí wọn jẹ koun padà silu òun, Nàìjíríà ni wọn ń bàa káàánú, tó sì dabi ẹni pé wọn jii gbé. 

Fọ́nrán kan ni arẹwà oṣere tíátà àti onkọrin náà gbé síta laipẹ yìí, tó ń wá ẹkún mú bí egbere wí pé kí wọn jẹ koun padà sílè, ìyẹn Nàìjíríà tòun ti wá. 

Ninu fọ́nrán náà tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ ni ẹni tó ń yà fọ́nrán náà tí ń sọ fún Angela wí pé kò tíì tó asiko ti yoo pada sílè. 

Ìlú Johannesburg ni orílẹ̀-èdè South Africa ni obìnrin arẹwà náà wá, tó ti ń sọ̀rọ̀, tí kò sì tíì sẹni tó lè ṣàlàyé nnkan tó gbé e debẹ, pẹ̀lú bí a ṣe gbọ.


Laipẹ yìí làwọn kan fẹ̀sùn kan Angela wí pé ipara ti wọn fi ń bo ara lo ń lo, èyí tí wọn loo hàn nínú ẹsẹ rẹ tó jóná. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI