GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ KÁÀKIRI ÀGBÁYÉ ṢAJỌYỌ AAWẸ RAMADAANI TO PARÍ, BẸ́Ẹ̀ LO SỌ PÉ KONIKALUKU ṢE ỌDÚN NÍNÚ ILÉ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 23, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ KÁÀKIRI ÀGBÁYÉ ṢAJỌYỌ AAWẸ RAMADAANI TO PARÍ, BẸ́Ẹ̀ LO SỌ PÉ KONIKALUKU ṢE ỌDÚN NÍNÚ ILÉ WỌN


Lónìí ní Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara báwọn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé ṣajọyọ aawẹ Ramadaani Ọlọdọọdun tó parí lónìí ọjọ́ Satide, ìyẹn Abamẹta.

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Gómìnà AbdulRazaq sọ pé konikaluku gbàdúrà nínú ilé wọn, kí wọn sì ṣe ayẹyẹ náà nínú ilé wọn pẹ̀lú lai káàkiri lọ sibikibi, nítorí pé eto konilegbele ṣí ń tẹsiwaju. 

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà, ó sọ pé "A kì àwọn èèyàn wa ẹlẹ́sìn Musulumi fún bí wọn ṣe parí aawẹ Ramadaani Ọlọdọọdun. A sì gbàdúrà wí pé ki Ọlọ́run Allah tó ga julọ tẹwọ gba àdúrà wa gẹ́gẹ́ bí a ṣe sì-ín, kò sì dárí àwọn aiṣedede wá jí wá. 

"A tún ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹmi gígùn àti àlàáfíà pípé láti kopa ninu aawẹ pelu ìgbàgbọ́ nínú rẹ."

Bakan naa lo tún sọ pé asiko Ramadaani jẹ́ asiko téèyàn ń fi gbogbo ara ati ọkàn sìn Ọlọ́run, èyí tó lo ń wẹ ọkàn mọ, tó sì ń kọ àwọn èèyàn láti kó ara wọn níjàánu. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI