B
o ti ṣe sọ pe ìṣòro nla lo maa n jé fáwọn eeyan lati mọ ìyàtọ̀ laarin olorin ẹsin gidi àtàwọn to n kọrin aye, Ustaz Abdul Ganiyu Muritadoh ti sọ pe alaimọkan ẹ̀dá nikan ni yoo maa kọrin ikọkukọ lati fi ṣi araye lọ́nà.
Loni-in, ọkan lara àwọn olorin ẹsin Islam to n ṣe daadaa nídìí iṣẹ ọhun ni Abdul Ganiyu Muritadoh, ẹni táwọn eeyan tun mọ si Owonikoko.
Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ilu Ogbomọṣọ nipinlẹ Ọ̀yọ́ ni gbajugbaju Aafa to nimọ Kurani yii n gbe, síbẹ̀ kaakiri làwọn eeyan ti mọ-ọn nílẹ̀ Yoruba latari orin aladun to ni waasi nla ninu to n kọ seti araye.
Ninu ifọrọwerọ ta a ṣe fun un laipẹ yii lo ti sọ pe, “Orin ti mo n kọ loni-in, lati kekere lo ti wa lara mi, mo tiẹ̀ le sọ pe, ohun ti mo jogun ba nile ni. Olorin gidi ni iya mi, Idayatu Adebisi, bẹẹ làwọn eeyan mọ wọn daadaa nigba ewe wọn, ṣùgbọ́n baba to bi mi lọmọ ni ko jẹ ki wọn tẹsiwaju daadaa nidii iṣẹ ọhun.
“Ohun ti wọn sọ nigba yẹn ni pe, àwọn ko le fara mọ ki iyawo àwọn maa kọrin kiri. Bi wọn ṣe jawọ ninu ẹ nìyẹn, ṣùgbọ́n ohun ti àwọn gbe silẹ nigba yẹn, lara mi gan-an ni Ọlọ́run ti ni ki ogo àti irawo yẹn buyọ.”
Saabe Anọbi gẹ́gẹ́ bi àwọn olólùfẹ́ ẹ ṣe tun maa n pe e ni igboro Ogbomọṣọ fi kun un pe, “Nigba ti baba tun ri i pe orin yẹn naa lemi gan an tun fẹ yan laayo, bi wọn ṣe lọ sọ mi si ile kewu nìyẹn, wọn ni Aafa onikuraani làwọn fẹ́ ki n ya, ki n le wulo daadaa fun Ọlọ́run Ọba.
“Lóòótọ́ ni mo kewu daadaa, ti àwọn eeyan si mọ mi gẹ́gẹ́ bi Aafa ti Ọlọrun maa n gbadura àwọn eeyan latara ẹ, ṣùgbọ́n orin ti Ọlọrun fun mi lẹ́bùn ẹ yii, ko fi mi silẹ.
“Mejeeji naa ni mo n ṣe, Aafa ni mi, bẹẹ ni mo tun jẹ́ akọrin ẹsin. Ọdún 2018 ni mo gbe rẹkọọdu mi àkọ́kọ́ jade, ti mo pe àkọlé ẹ ni Message, okiki rẹkọọdu yẹn kan daadaa pẹ̀lú. Bi àwọn eeyan ṣe n pe mi ni olorin, bẹẹ ni mo n ṣíṣẹ Aafa daadaa ti ọkan ko si di ikeji lọ́wọ́.”
Ni bayii, rẹkọọdu meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Aafa Owonikoko n ṣíṣẹ le lori.
O ni, “Kani ki i ṣe gbogbo rọti-rọti to wa lagbaye loni-in, o yẹ ka ti pari rẹkọọdu ọhun, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ yii gan-an pẹ̀lú ohun ti a maa yannana ẹ ninu awo orin wa to n bọ.
“Idaamu nla lo ba agbaye o, bẹẹ ọmọ eeyan lo ṣokunfa afọwọfa oríṣiríṣi ohun to n de ba wọn. Ẹṣẹ ti Ọlọrun ni ka jinna si lawa ọmọ eeyan n ṣẹ, fun idi eyi, a nilo aforiji pupọ, bẹẹ làwọn eeyan lapapọ, yala Musulumi tabi awọn ẹlẹ́sìn yooku nilo ọ̀rọ̀ iṣiti, orin to ni waasi ninu, ki aye wa le dara, ki a kuro ninu iwa ẹṣẹ.”
GM Islamic Music International Entertainment ni Aafa Abdul Ganiyu Muritadoh pe orúkọ ẹgbẹ́ akọrin ẹ, bẹẹ lo fidi ẹ múlẹ̀ ninu ọrọ ẹ pe, o ṣe pataki ki eeyan kewu daadaa to ba fẹ jẹ ọjọgbọn nla ninu orin Islam.
“Orin ẹsin la pe e, kii ṣe orin aye, fun idi eyi, ọrọ iṣiti latinu Qur’an la gbọ́dọ̀ maa fi ṣe waasi orin, ati pe àwọn ti wọn n kọ ikọkukọ loni-in ninu orin ẹsin, alaimọkan ti ẹsin ko yẹ ni wọn o, bẹẹ awa ta a ba jẹ́ Afaa ninu olorin gbọ́dọ̀ yàtọ̀ daadaa.”
No comments:
Post a Comment