GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ TÚN GBÀRÀDÁ L'ORI ILÉÈWÉ TÍ WỌN ṢẸ̀ṢẸ̀ PARÍ KÍKỌ́ RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 23, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ TÚN GBÀRÀDÁ L'ORI ILÉÈWÉ TÍ WỌN ṢẸ̀ṢẸ̀ PARÍ KÍKỌ́ RẸ̀


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, àdúrà làwọn ara agbegbe Ballah tó wà ni ìjọba ìbílẹ̀ Ásà ń gba fún Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lórí bo ti ṣe parí kíkọ ilé-ẹkọ girama tàwọn ọlọ́pàá.

Ile-ẹkọ náà là gbọ pé ó jẹ́ tijọba ipinlẹ náà, èyí tí wọn pé ní Government Secondary School, tí wọn sì ti yí orúkọ rẹ padà sí Police Secondary School báyìí. 


Èyí pẹ̀lú àwọn àkànṣe àtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ tijọba dawọ lè látìgbà tó ti Gomina AbdulRazaq tí de ori ipò. 

Ohun to ń yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu ni bo ṣé jẹ́ pé asiko konilegbele tó ń lọ lowo nijọba rí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti tètè parí àwọn àkànṣe iṣẹ láti fi saami ayẹyẹ ọdún kan ìjọba rẹ.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI