ÌDÙNNÚ ṢUBÚ LU AYỌ̀ NI KWARA BÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE GBÉ MILIỌNU LỌ́NÀ ỌỌDUNRUN NÁÍRÀ SILẸ F'ÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 5, 2020

ÌDÙNNÚ ṢUBÚ LU AYỌ̀ NI KWARA BÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE GBÉ MILIỌNU LỌ́NÀ ỌỌDUNRUN NÁÍRÀ SILẸ F'ÁWỌN ARÁÀLÚ


Inu ìdùnnú àti ayọ ńlá làwọn ara ipinlẹ Kwara wá bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn lórí bí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ náà ṣe bù ọwọ lu obitibiti owó fún iranlọwọ aráàlú lásìkò konilegbele yìí. 

Bí tilẹ̀ jẹ́ pé eto naa ti wá nínú ìpinnu Gómìnà AbdulRazaq tẹle, ṣùgbọ́n tó rí i pé asiko gidi re e láti mú ìpinnu náà ṣe, tó sì bù ọwọ lu ọọdunrun miliọnu {300,0000,000} náírà láti fi rán àwọn èèyàn lọ́wọ́. 

Lára àwọn tí yóò jẹ àǹfààní nínú owó yìí làwọn arúgbó, oníṣòwò kéékèèké, awakọ àtàwọn tó kú díẹ̀ kaato fun láwùjọ.


Kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣunna n'ipinlẹ náà, Arábìnrin Oyeyẹmi Ọlasumbọ Florence lo sọ̀rọ̀ náà jáde wí pé ìjọba tí bù ọwọ lu owó náà fún ẹ̀ka eto ti wọn pé ní Kwara State's Social Investment Programme (KWASSIP), èyí tí wọn fi ń ṣe iranwọ fáwọn aláìní, èyí tí Mohammed Brimah jẹ́ alakoso ẹ. 

Oyeyẹmi sọ pé ọ̀nà láti gbé àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún láwùjọ re e, to sì jẹ kò di mimọ pé àwọn awakọ tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ni wọn yóò pín ọgọ́rùn-ún miliọnu náírà nínú owó náà gẹ́gẹ́ eto ẹyawo tí wọn pé ní 'Owó Ìṣòwò'.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI