LẸ́YIN ỌDÚN KAN ATAABỌ, WỌN DÁ ẸJỌ IKÚ FÚN ỌLÁLÉKAN L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 5, 2020

LẸ́YIN ỌDÚN KAN ATAABỌ, WỌN DÁ ẸJỌ IKÚ FÚN ỌLÁLÉKAN L'EKOO


Ọjọ́ Mọnde àná ni ile ẹjọ́ akanda-ẹṣẹ {Special Offences Court} l'Ekoo dá ẹjọ́ ikú fún Ọlalekan Hameed tí wọn lo o jí owó ọga rẹ, tó sì tún ṣekú pá ọga náà dànù. 

Ọjọ́ kinni-in oṣù kejìlá ọdún 2018 là gbọ pé Ọlalekan lọọ ja ọga rẹ, Jọlasun Okusanya, ẹni ọdún mẹrindinlọgọrin lólè owó ọtadín-nígbà {$117} owó dọla àti miliọnu kan náírà dín-lẹgbẹrun-un-lọna-aadọta {N950,000}. 

A gbọ pé olóògbé náà kò sì nítòsí lásìkò tí Ọlalekan tó yàn iṣẹ awakọ láàyò wọlé jí owó náà, ṣùgbọ́n tó ká a mọbẹ. Bó ṣe rí í pé àṣírí òun ti tú lo mú kó gun olóògbé náà pá, tó sì na pápá bora.

Plot 83 Owukori Crescent, Alaka Estate, Surulere, Ekoo niṣẹlẹ náà tí wáyé ní nǹkan bí aago méjìlá aabọ ọ̀sán ọjọ́ náà. 

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlalekan sọ pé ẹgbẹ̀rún kan náírà lásán lòun jí lọ́jọ́ náà, àti pé òun kò mọ nnkan kan nípa ikú ọga òun, ṣùgbọ́n òun táwọn ẹlẹrii tó tako ó sọ ní pe irọ lo pá. 

Wọn ní làwọn èèyàn rí Ọlalekan lásìkò náà, àti pé fẹnsi ilé náà lo gba salọ lọ́jọ́ náà. 

Onidajọ Mojisọla Dada nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ sọ pé Ọlalekan jẹbi àwọn ẹ̀sùn olè jíjà àti iṣekupani tí wọn fi kan án, ìdí re e tó fi ní kí wọn lọ yẹgi fún Ọlalekan ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI