Ọjọru, tii se Wẹside àná n'ijọba ipinlẹ Ogun lábẹ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun gbé àwọn nǹkan irinsẹ amuṣẹya fun ileeṣẹ eleto ààbò ipinlẹ náà, ìyẹn Social Orientation and Safety Corps {So-Safe Corps} láti lè jẹ ki iṣẹ eto ààbò túbọ̀ kẹsẹjari.
Nigba tó ń fìdí rẹ múlẹ̀ fún AWÍKONKO lẹ́yìn eto naa, agbẹnusọ fún ileeṣẹ So-Safe Corps, Ògbẹni Mọruf Yusuf sọ pé lára àwọn nǹkan irinsẹ t'ijọba fi tà àwọn lọrẹ ni mọto {Pick-up Van} àti ọkada agberapa {Motorbikes} mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ọna láti mọ rírí àti ipa tí ileeṣẹ eleto ààbò náà ń kó láti dẹ́kun ìwà ibajẹ àti ọ̀daràn káàkiri ipinlẹ Ogun lo mú k'íjọba fáwọn ẹ̀bùn náà tá wọn lọrẹ, gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ.
Ọga pátápátá fún ileeṣẹ náà, Kọmanda Sọji Ganzallo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun lórí igbesẹ yìí, tó sì ṣèlérí wí pé ileeṣẹ náà yóò túbọ̀ máa gbé ògo ipinlẹ Ogun ga lẹka eto ààbò.
No comments:
Post a Comment