NÍTORÍ ẸSUN JÌBÌTÌ, EFCC WỌ AKỌ̀WÉ ÀGBÀ LỌ SÍLÉ ẸJỌ́ L'ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 13, 2020

NÍTORÍ ẸSUN JÌBÌTÌ, EFCC WỌ AKỌ̀WÉ ÀGBÀ LỌ SÍLÉ ẸJỌ́ L'ỌYỌ


Bí ilé-ẹjọ́ gíga t'ipinlẹ Ọ̀yọ́ bá fi ríi pé akọwe àgbà l'ẹka ètò iṣẹ àgbẹ̀ àti ọgbin, Rasaq Kọlawọle jẹbi ẹ̀sùn jìbìtì tí àjọ tó ń gbógun ti ìwà ajẹbanu, EFCC fi kan an, afaimọ ni kò má jẹ́ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wàhálà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò parí sì. 

Ẹsun jìbìtì owó miliọnu mẹ́rin àti irínwó {N1.4m} náírà ni Rasaq Kọlawọle lu ẹnìkan tí wọn pé orúkọ ẹ ní Ibikunle Alongẹ pẹ̀lú ayédèrú ilẹ̀ tó tá fún un.

Oni, tí i ṣe Wẹside ni àjọ EFCC fi ojú bàbà náà bá ilé-ẹjọ́ náà tí Onidajọ Aderonkẹ Aderẹmi tí jẹ adajọ. 

AWÍKONKO gbọ pé ilẹ̀ kan tó wà lágbègbè Alabata Olosoko, Moniya n'ilu Ibadan ni Rasaq tá fún Alongẹ, tó sì padà ríi pé ayédèrú ilẹ̀ lo tá foun. 

Wọn ní ẹnikan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Arábìnrin Ali, ẹni tó ti doloogbe lo ni ilẹ̀ náà, ìdí re e tó fi kọ ìwé ẹsun sì àjọ EFCC láti ṣe ìwádìí. 

Kọlawọle nínú ọ̀rọ̀ rẹ sọ pé òun kò jẹbi pẹ̀lú àwọn alaye, ṣùgbọ́n tí Onidajọ Aderẹmi sún igbẹjọ mi-in síwájú di ọjọ́ kẹrinlelogun àti ọjọ́ karundinlọgbọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI