IṢẸ́YÁ! KWARA PARI GBOGBO ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA {AWORAN} - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 13, 2020

IṢẸ́YÁ! KWARA PARI GBOGBO ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA {AWORAN}


Gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba pátápátá tó wà káàkiri ipinlẹ Kwara lo tí de èbúté yiyanju bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, tó sì ń jẹ ìyàlẹ́nu ńlá fún pupọ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé lórí igbesẹ yìí.

Ohun tó ń jẹ ki awọn àkànṣe iṣẹ tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ náà dawọle máa jẹ ìyàlẹ́nu fáwọn èèyàn ni bo ṣe jẹ́ pé àsìkò tí pupọ àwọn ìjọba ipinlẹ káàkiri dawọ iṣẹ dúró lásìkò konile-o-gbele yìí ni ìjọba Kwara rí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti tètè parí iṣẹ.

Lara àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó ti dé èbúté ìparí ni ilé-ẹ̀kọ́ girama tí Oro níbi tí minisita foro ìròyìn àti àṣà lorilẹ-ede yìí, Alaaji Lai Mohammed ti wá, ilé-ẹ̀kọ́ girama tí Ilọrin tó wà lágbègbè Geri-Alimi àtàwọn mi-in tí kò dín ni ọgbọ́n.

Ko sẹni to ń rí ipò táwọn ilé-ẹ̀kọ́ káàkiri ipinlẹ Kwara wá tẹ́lẹ̀, tí kò níí banujẹ nítorí gbogbo rẹ lo tí bajẹ kọjá sísọ. Ṣùgbọ́n ní báyìí, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ náà tí dùn-ún wo lójú, táwọn èèyàn sì ń sọ pé rẹgẹ ni wọn ba ti ìgbàlódé àsìkò yìí mú.

Díẹ̀ re e lára àwọn àwòrán ibi tí iṣẹ de duro: 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI