KÓNÍLÉGBÉLÉ! NÍTORÍ EBI, BAALE ILÉ POKUNSO SÍNÚ YÀRÁ RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 2, 2020

KÓNÍLÉGBÉLÉ! NÍTORÍ EBI, BAALE ILÉ POKUNSO SÍNÚ YÀRÁ RẸ̀


Igbe àti ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu àwọn ará agbegbe Umudafa, Awo Mbieri tó wà n'ijọba ìbílẹ̀ Mbaitoli, ipinlẹ Imo lọ́jọ́ Tọside ijẹta nígbà tí wọn déédéé rí òkú baálé ilé ẹni ọdún marundinlaadọta kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Osita Ezuruike. 

Ko si nnkan méjì tí wọn lo o jẹ ki Osita gba ẹmi ara rẹ bí kò ṣe bí ìjọba ṣe ń fi ọjọ́ kún àsìkò konilegbele tí yóò parí lọ́jọ́ Mọnde ọ̀sẹ̀ to ń bọ̀ yìí. 


Igbe 'ebi yìí pọ ju' là gbọ pé Osita ń pariwo láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n táwọn èèyàn kò kọbi ara sì í. 

Ìyàlẹ́nu lo jẹ nígbà táwọn èèyàn rí òkú rẹ níbi tó pokunso sì í lórí faanu, tó sì ń min jolonjolo. 

Lójú ẹsẹ làwọn èèyàn ti ranṣẹ sáwọn ọlọ́pàá láti wá a gbé òkú rẹ kúrò lọ sí mọṣuari. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI