WÀHÁLÀ DE! WỌN TÚN TÍ RÍ AARUN KORONAFAIRỌỌSI LÁRA ÈÈYÀN MÉJÌ NÍ FMC ABẸ́ÒKÚTA, ÈÈYÀN KAN TÍ KÙ NÍNÚ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 2, 2020

WÀHÁLÀ DE! WỌN TÚN TÍ RÍ AARUN KORONAFAIRỌỌSI LÁRA ÈÈYÀN MÉJÌ NÍ FMC ABẸ́ÒKÚTA, ÈÈYÀN KAN TÍ KÙ NÍNÚ WỌN


Bí ìròyìn to tẹ AWÍKONKO lọ́wọ́ lalẹ òní Satide bá fi lè jẹ òtítọ́, a jẹ pe afaimọ kí Gómìnà Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun má tún sún konilegbele síwájú pẹ̀lú bí wọn ṣe ni wọn ti rí èèyàn méjì tó tún ti ní aarun Covid-19 ni ọsibitu FMC tó wà ní Idi-Aba, Abẹ́òkúta. 

AWÍKONKO gbọ pé ọjọ́ Mọnde tó kọjá yìí ni wón gba ẹ̀jẹ̀ àwọn méjì kan tí wọn fura si pe aarun náà wá lára wọn láti yẹ ẹ wo, èyí tí wọn ní alaboyun kan náà wá lára wọn. 

Òní ni esi àyẹ̀wò náà jáde, tó sì fi idi rẹ múlẹ̀ wí pé àwọn méjèèjì ní wón ti ní aarun koronafairọọsi, ìyẹn Covid-19. 

A gbọ pé látìgbà tí wọn tí dá àwọn méjì yìí dúró lọ́jọ́ Mọnde náà làwọn dọkita àtàwọn nọọsi tí ń gbé wọn láti wọọdu kan bọ sì wọọdu mi-in, ìyẹn ni ETR àti Gynaecology Emergency. 

Alaboyun náà là gbọ pé ó ti dá gbere fàyè kí esi ayẹwo rẹ tó o jáde lónìí, tí wọn sì ni ẹnikan yòókù tó jẹ́ ọkùnrin tí wá ní yàrá ààbò, ìyẹn Isolation Centre tí wọn gbé e pamọ sì. 

Gbogbo àwọn nọọsi àti dọkita tí wọn dá àwọn èèyàn yìí lóhùn là gbọ wọn tí kò wọ yàrá ààbò fún ìtọ́jú, tí wọn sì làwọn kan tí na pápá bora ni kété tí ìròyìn náà jáde síta. 

Bákan náà, gbogbo akitiyan láti bá Dọkita Ashimi tí a gbọ pé òun ló ń tọju àwọn èèyàn nibẹ sọ̀rọ̀ lo ṣí ń jà sì pàbó títí tá a fi parí ìròyìn yìí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI