Gbajugba oṣere tiata Yoruba nni, Dayọ Amusa bu sẹkun lori b'awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ṣe kọ lati fun ara wọn laaye, gẹgẹ bi imọran t'ijọba at'awọn ileeṣẹ eleto ilera ṣe la a kalẹ gẹgẹ ọna lati dẹkun itankalẹ aarun Covid-19.
Ori ikanni Instagram l'obinrin naa ti bu sẹkun wi pe loootọ ni aarun koronafairọọsi, to si lo o ṣe oun laaanu gidigidi wi pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi n sọ pe irọ ni.
Dayọ ni o ṣe pataki f'awọn eeyan lati maa yago fun ara wọn, nitori pe loootọ ni aarun naa wa nita, ati pe ko rọrun f'awọn to n kagbako aarun naa rara.
No comments:
Post a Comment