DINO MELAYE FI ẸNU KỌ, L'AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA BA SỌRỌ BURUKU SI I - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 6, 2020

DINO MELAYE FI ẸNU KỌ, L'AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA BA SỌRỌ BURUKU SI I

Kani gbajugbaja Sẹnetọ to fẹran afẹfẹ-yẹyẹ nni, Sẹnetọ Dino Melaye mọ pe ọrọ naa yoo pada yi le oun lori ni, boya ko ba ti gbe ẹnu rẹ dakẹ, nitori pe titi aye ni yooo fi maa ranti ọjọ karun, ọsu karun-un ọdun yii.

Ana ti i ṣe Tuside ni Sẹnetọ tẹlẹri n'ipinlẹ Kogi naa, Melaye gbe e sori ikanni ayelujara rẹ wi pe o yẹ ki oju ti oun at'awọn adari ilẹ Naijiria pẹlu bi wọn ko ṣe le f'awọn araalu ni nnkan ti wọn n fẹ lasiko yii.

Melaye ni "Gbogbo ẹni to ti f'igba kan ri jẹ adari tabi di ipo kan mu at'awọn to ṣi n di ipo mu lọwọlọwọ lorilẹ-ede Naijiria, yala wọn dibo yan wọn ni tabi ijọba lo yan wọn sibẹ, titi d'ori emi naa la ti kuna patapata.

"Ọdun mẹrinlelọgọta (64years) la fi ta epo rọbii, a ko si lẹbọ awọn araalu fun ọsẹ meji pere ti konilegbele fi wa nita!! Ohun to daju ni pe Ọlọrun awọn mẹkunnu yoo dajọ fun gbogbo wa patapata. Asiko re e lati tun ero wa pa.

Bi Melaye ṣe sọrọ yii tan l'awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si i sọrọ buruku si i wi pe oun gan an lo yẹ ki idajọ Ọlọrun bẹrẹ lori ẹ, nitori pe gbogbo owo araalu lo fi n ra mọto, to si fi n kọ ile kaakiri.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI