NÍTORÍ ÌWÀ ÀÌGBỌRÀN ÀWỌN ARÁÀLÚ! GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN FI ỌSẸ KAN KÚN KÓNÍLÉGBÉLÉ N'IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 15, 2020

NÍTORÍ ÌWÀ ÀÌGBỌRÀN ÀWỌN ARÁÀLÚ! GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN FI ỌSẸ KAN KÚN KÓNÍLÉGBÉLÉ N'IPINLẸ OGUN


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun tí so pé kò sí nnkan tòun tún lè ṣe láti lè tètè jẹ́ kí àrùn aṣekupani Covid-19 kasẹ nilẹ bí kò ṣe pé koun tún fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko kún konile-o-gbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.

Lónìí ní Gomina Abiọdun sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń báwọn akọroyin n'ipinlẹ Ogun sọ̀rọ̀ ni ọfiisi rẹ tó wà ní Oke-Mọsan, Abẹ́òkúta. 

O sọ pe nígbà tòun sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn nípa àrùn koronafairọọsi, pàápàá ti konile-o-gbele, ọgọ́rùn-ún kan làwọn tó ti ní àrùn náà lára, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Tọside àná, àwọn tó ti ní àrùn náà tí lè ní mẹrinlelọgbọn ni ọgọ́rùn-ún kan {134} láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

Gómìnà fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé ojoojumọ làwọn ṣàyẹ̀wò fáwọn aráàlú, tó sì jẹ pe àwọn tí kò dín ni irínwó àti àádọ́ta {450} làwọn ń yẹwo lojumọ, táwọn sì tún ti fi kún agbára àwọn òṣìṣẹ́ láti tẹsiwaju. 

Ọ ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikilọ ìjọba àtàwọn agbófinró nípa isunmọra-ẹni, ìyẹn Social distancing, síbẹ̀ ó làwọn aráàlú ṣí ń sunmọ ara wọn gidigidi, pàápàá láàárín ọjà. 

Dapọ Abiọdun làwọn aráàlú lo ṣí ń jáde lai lo ibomu, táwọn ọlọkada ń gbé ju èrò kan lọ, táwọn awakọ taisi náà sì ń gbé ju èrò mẹ́ta lọ. 

Bákan náà lo ni àwọn ọgọ́rùn-ún kan lè ní mẹ́jọ làwọn tọwọ tí tẹ, tí wọn lugbadi òfin konile-o-gbele àti isunmọra-ẹni, tí wọn sì ti fojú bá ilé ẹjọ. Bẹ́ẹ̀ lo ni àwọn mọto ẹẹdẹgbẹta lè ní mẹtadilogun {517} làwọn ọlọ́pàá tí gba, tí wọn sì ti gbà ọkada ọgọ́rùn-ún lè ní mẹ́sàn-án {109}, to fi mọ kẹkẹ maruwa mẹ́fà. 

O ni gbogbo èyí kò lè jẹ ki àrùn náà tètè kasẹ nilẹ báwọn ṣe ń fẹ́, ìdí re e tó fi lòun yóò fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko kún-un. 

Lákòótán, ó ní ìjáde ṣí wá bíi ti tẹ́lẹ̀, ìyẹn lọ́jọ́ Mọnde, Wẹside àti Fraide láàárín aago méje sì márùn-ún irọlẹ títí di ọjọ Àìkú, Sande, ọjọ́ kẹrinlelogun. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI