Epe ńlá-ńlá làwọn ara agbegbe Fẹsọjaye tó wà ní Ọwọade lójú ọ̀nà Iléṣà, Oṣogbo ń gbé ìyálé ilé kan tí wọn ń pè ní Ìyá Ayọ ṣẹ lórí bo ṣe so ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́wàá mọ́lẹ̀ sínú àpò ṣaka bí ẹranko.
Ìyá Ayọ ni wọn loo sọ pé ẹ̀mí èṣù ń dá ọmọ náà láàmú, tó sì dee mọ́lẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́rin gbáko kí àṣírí tó o tú.
Ọjọbọ tí i ṣe Tọside ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni wọn ní obìnrin náà tí de ọmọ rẹ̀ mọ́lẹ̀, tó sì jẹ pe ọjọ́ Àìkú, ìyẹn Sande làwọn ara àdúgbò rí ọmọ náà níbi tó wà, tó ń bẹbẹ fún iranlọwọ.
Ẹni tí àṣírí náà tú sí lọ́wọ́ lo lọ fi tó àwọn àgbààgbà àdúgbò, tí wọn sì lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá Oke-Baalẹ létí. Ṣọọṣi là gbọ pé wọn tí lọ gbé Ìyá Ayọ
Lára àwọn tó gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì AWÍKONKO létí fi yẹ wá pé ẹ̀mí òkùnkùn tó wọnú ọmọ òun ló jẹ́ kó máa ja olè káàkiri, tòun kò sì fẹ́ kó jalè mọ.
No comments:
Post a Comment