BUHARI, ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC WÒ WÀHÁLÀ TUNTUN NÍTORÍ JÌBÌTÌ BILIỌNU MEJIDINLAADỌTA NÁÍRÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 21, 2020

BUHARI, ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC WÒ WÀHÁLÀ TUNTUN NÍTORÍ JÌBÌTÌ BILIỌNU MEJIDINLAADỌTA NÁÍRÀ


Àṣírí jìbìtì owó ńlá kan ló tún ti tú báyìí lábẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ Muhammadu Buhari báyìí. Biliọnu mejidinlaadọta {N48b} náírà ni wọn pé owó náà tí wọn loo pòórá nileeṣẹ ìjọba tó ń rí sọ̀rọ̀ àgbẹ̀ àti ọ̀gbìn lorilẹ-ede yìí.

Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, ìyẹn Peoples Democratic Party, and PDP lọ tú àṣírí ńlá náà síta fáwọn ọmọ Nàìjíríà nínú atẹjade tí agbẹnusọ ati akọwe ìpolongo ẹgbẹ́ náà, Ọgbẹni Kọlawọle Ọlọgbọndiyan fi síta.

Ọlọgbọndiyan sọ pé àwọn àṣírí tí akọ̀wé àgbà nileeṣẹ náà, Dọkita Umar Bello tú síta níbi ifọrọwerọ tí wọn ṣe fún un lo tí fìdí rẹ múlẹ̀ nípa àwọn jìbìtì tí wọn tí lu lórí ilẹ̀ ńlá tí wọn kò, èyí tí owó rẹ jẹ biliọnu méje lè díẹ̀ {N7.044}, tí kò sì tíì parí lábẹ́ ìjọba Ààrẹ Buhari. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI