ỌNỌREBU ỌLABỌDE F'ÁWỌN ONIROYIN L'OUNJẸ L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 6, 2020

ỌNỌREBU ỌLABỌDE F'ÁWỌN ONIROYIN L'OUNJẸ L'ABẸOKUTA


Ọkàn lára àwọn gbajumọ Ọnọrebu n'ilu Abẹ́òkúta, Ọnọrebu Ọmọyẹle Ọlabọde lónìí fáwọn oniroyin l'ounjẹ konilegbele láti fi mọ rírí ipa tí wọn ń ko láwùjọ.

Ọgbà ilé ẹgbẹ́ náà tó wà ní Ìwé-Ìròhìn, Oke-Ilewo n'ilu Abẹ́òkúta ni eto rampẹ náà tí wáyé laarọ òní, Ọjọru, ìyẹn Wẹside. 

Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ fún pupọ àwọn oniroyin tí wọn jẹ àǹfààní oúnjẹ àti owó tí Ọnọrebu Ọlabọde tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oludije sílé igbimọ aṣofin n'ilu Abuja {House of Representatives} lọ́dún tó kọjá lábẹ́ asia ẹgbẹ́ òṣèlú ADC náà pin, nítorí pé wọn kò níí lérò tẹ́lẹ̀.

Ohun tó ń jẹ ki nnkan ìwúrí yìí yà àwọn oniroyin lẹ́nu ni pé Ọnọrebu Ọlabọde fìdí rẹmi níbi ìdìbò ọdún tó kọjá, tó sì tún ń mọ rírí ipa àwọn oniroyin, pàápàá lásìkò konilegbele yìí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI