ẸGBẸ́ ELETO ÌLERA, NMA GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ NÍTORÍ OWÓ AJẸMỌNU OJÚMỌ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 6, 2020

ẸGBẸ́ ELETO ÌLERA, NMA GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ NÍTORÍ OWÓ AJẸMỌNU OJÚMỌ́


L'ọjọ Iṣẹgun, Tuside àná ni ẹgbẹ́ àwọn oniṣẹgun òyìnbó, ìyẹn Nigerian Medical Association (NMA), ẹ̀ka t'ipinlẹ Kwara gbé oṣuba káre fún Gómìnà ipinlẹ náà, AbdulRahman AbdulRazaq lórí ìlérí mi-in tó tún mú ṣẹ láti fáwọn eleto Ilera lowo iṣẹ ojúmọ́.

Gómìnà AbdulRazaq lo bù ọwọ luu pé kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera tó bá ń jáde lojoojumọ fun ìpolongo láti dẹkun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19 máa gba owó tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún marundinlọgbọn {N25,000} náírà lojoojumọ.

Èyí ni Gomina AbdulRazaq fi ń mọ rírí ipa táwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ń ko lásìkò tí aarun koronafairọọsi ń bá agbaye, pàápàá Nàìjíríà fínra.

Dọkita Kọlade Ṣọlagberu to jẹ́ alaga ẹgbẹ́ NMA ló ṣiṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà wí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí ń rí owó náà gbà báyìí. Dọkita Ṣọlagberu sọ pé owó náà kì í ṣe owó oṣù bí kò ṣe owó ajẹmọnu ojoojumọ t'ijọba ṣèlérí fún wọn.

O ni nnkan iwuri ńlá ni Gomina AbdulRazaq ṣe yìí, tó sì ń yà àwọn lẹ́nu wí pé Gomina mú ìlérí rẹ ṣẹ, tó sì fi ń dá ìjọba lójú wí pé aarun burúkú náà yóò d'ohun ìgbàgbé pátápátá laipẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI