AKEREDOLU DA GBOGBO AWỌN OṢIṢẸ IGBAKEJI RẸ DURO LOJIJI, L'OUN NAA BA N'IJA ṢẸṢẸ BẸRẸ NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 24, 2020

AKEREDOLU DA GBOGBO AWỌN OṢIṢẸ IGBAKEJI RẸ DURO LOJIJI, L'OUN NAA BA N'IJA ṢẸṢẸ BẸRẸ NI


Ara ko r'okun, bẹẹ ni ara ko ro adiẹ l'ọrọ naa n jẹ bayii laaarin Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Agboọla Ajayi lori b'awọn mejeeji ko ṣe gba ti ara wọn mọ lasiko yii.

Ọjọ Aje, iyẹn Mọnde to kọja yii ni igbakeji gomina Akeredolu, iyẹn Ajayi kede sita wi pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ati pe oun ko le ba ẹgbẹ oṣelu APC toun wa ninu rẹ tẹlẹ ni nnkan an ṣe papọ mọ.
Ṣaaju asiko yii ni ija abẹle ti wa laaarin Akeredolu ati Ajayi, ti wọn si l'awọn mejeeji kii fi ọrọ lọ ara wọn mọ, eyi to si han si gbogbo awọn araalu pe aarin awọn mejeeji ti daru.
Bẹo ba gbagbe, l'ọjọ Satide, Abamẹta to kọja ni Gomina akeredolu paṣẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Bọlaji Salami pe ko gbọdọ gba Ajayi laaye lati kuro ninu ile ijọba, eyi ti a gbọ pe wọn fa fun bi i wakati mẹrin.

Ṣugbọn l'ọjọ keji rẹ ni akọwe gomina gbe atẹjade sita wi pe Gomina Akeredolu ko mọ nnkankan nipa bi kọmiṣanna ọlọpaa ṣe dena de Ajayi lati ma kuro ninu ile ijọba lalẹ ọjọ naa, ati pe Ajayi funra rẹ lo n ya fiimu lati fi ba Akeredolu l'orukọ jẹ, eyi t'awọn eeyan n sọ pe ọkunrin naa ko mọ ohun to n sọ nitori pe ọrọ to han si gbogbo agbaye ni.

L'ọjọ Iṣegun ti i ṣe Tuside ana ni Akeredolu jawe gbele ẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ igbakeji rẹ wi pe ijọba ko nilo wọn mọ, ṣugbọn ni kete ti iroyin naa tẹ Ajayi lọwọ, lo ti sọ pe bi gomina ba da wọn duro, agbara t'oun naa gbe e lati gba wọn pada sẹnu iṣẹ, toun yoo si maa san owo oṣu fun wọn l'apo ara oun.

Idunkooko ta a gbọ pe o n ṣẹlẹ bayii ni bi wọn ṣe sọ pe Akeredolu ti ni ki igbakeji rẹ, Ajayi kọ'we f'ipo silẹ gẹgẹ bi igbakeji rẹ, ṣugbọn ti wọn i Ajayi n sọ pe ko ṣee ṣe, ati pe awọn yoo jọ lo saa iṣakoso yii tan ni.
 
Agbẹnusọ gomina, Ọgbẹni Ṣẹgun Ajiboye f'idi ẹ mulẹ pe loootọ ni Gomina Akeredolu ti da gbogbo awọn oṣiṣẹ igbakeji rẹ duro, to si ti ni ki wọn maa lọ sile.
Awọn ti da duro naa ni Olomu Bayọ, amugbalẹgbẹ lori akanṣe iṣẹ (special duties); Allen Ṣoworẹ, amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin; Ọlawale Mukaila, amugbalẹgbẹ lori fọto yiya; Babatọpẹ Ọkẹowo, igbakeji akọwe; Samuel Ogunmusi; Omotunmiṣe Tokunbọ ati Ẹrifeyiwa Akinnugba t'awọn jẹ maugbalẹgbẹ iyawo igbakeji gomina.
Ọkẹowo n'igba to n sọrọ sọ pe loootọ gomina ti da awọn duro, ṣugbọn ẹni t'awọn n ṣiṣẹ fun ti sọ pe kawọn pada sẹnu iṣẹ, t'awọn si ti pada loju ẹsẹ.

AWIKONKO gbọ pe igbakeji gomina yii, Ajayi naa n gbiyanju lati jade su ipo gomina nípinlẹ Ondo ninu idibo to n bọ lọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI