AWỌN AṢIRI TẸ O MỌ NIPA DAN FOSTER, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ TO TẸRI-GBAṢỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 18, 2020

AWỌN AṢIRI TẸ O MỌ NIPA DAN FOSTER, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ TO TẸRI-GBAṢỌ


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja sọrọsọrọ ori afẹfẹ nni, Daniel Foster ti jade laye, ti iroyin iku rẹ si n jẹ kayeefi fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye.

Aarọ ana ti i ṣe Ọjọru, iyẹn Wẹside ni Daniel Foster gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo ṣee ṣe ko jẹ arun koronafairọọsi lo pa a. Ẹni ọgọta ọdun ni Dan Foster n'igba to ku.

Ogbontarigi ni Dan Foster jẹ nidi iṣẹ igbohunsafẹfẹ, paapaa nilu Eko, ti ọpọ awọn sọrọsọrọ si ti ti ara rẹ dide.

Lara awọn ohun to mu Dan Foster, ẹni ti wọn tun n pe ni Big Dawg gbajumọ, to si mu k'awọn eeyan fẹran rẹ daadaa ni ti ohun (voice) to ni.

Kaakiri orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n gbe oṣuba kare fun oloogbe yii, ko da, t'awọn oyinbo naa tun maa n ṣe sadankata fun-un.

Inufẹdọ ni Dan fi n ṣiṣẹ n'ileeṣẹ redi Cool, iyẹn Cool FM, to si maa n pe awọn ero rẹpẹtẹ wa sibi apẹjọ ọlọdọọdun kan ti wọn maa n ṣe, eyi ti wọn pe ni Praise Jam.

Washington D.C tilẹ Amẹrika ni wọn bi Dan Foster si, to si lọ sile-ẹkọ giga ti Morgan, iyẹn Morgan State University nibi to ti kẹkọọ nipa iṣẹ igbohunsafẹfẹ ati tiata, ṣugbọn ọdun 2000 lo de sorilẹ-ede Naijiria, latigba naa lo si ti wa pẹlu ileeṣẹ redio Cool.

Yatọ si pe Daniel n ṣiṣẹ nileeṣẹ redio Cool FM, o tun ti ṣiṣẹ l'awọn ileeṣẹ redio nla-nla bii Cathy Hughes Radio One, Virgin Island, Cool FM, Classic FM ati City FM, Lagos.

Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni oloogbe yii gba ami-ẹyẹ, iyẹn Nigeria Media Merit Award, ti ọdun 2003, 2004 ati 2005 gẹgẹ bi sọrọsọrọ to dara julọ, bẹẹ lo tun gba ami-ẹyẹ City People ti ọdun 2004 ati 2005.

Ọkan lara awọn adajọ ti idijẹ Idols West Africa t'ọdun 2007 ni Dan Foster.

Awọn gbajugbaja lagbo amuludun bii J.J Omojuwa, Bovi, Frak Edoho, Do2tun at'awọn mi-in ni wọn ti n banujẹ lori ayelujara latari iku rẹ

Lovina Foster ni orukọ iyawo rẹ, ti Ọlọrun si yọnda ọmọ mẹta fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI