AYE LE O! KỌMIṢANNA NAA TUN LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI L'ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 26, 2020

AYE LE O! KỌMIṢANNA NAA TUN LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI L'ỌYỌ


Kọmiṣanna to kere julọ n'ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeun Fakorede naa ti lugbadi arun aṣekupani Covid-19 bayii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Fakorede to jẹ kọmiṣanna f'ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya la gbọ pe ayẹwo ti wọn ṣe fun un fi han pe o ti lugbadi arun naa, to si ti jẹ ko ye gbogbo eeyan wi pe oun ti lọ farapamọ fungba diẹ lati tọju ara oun.

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa lo f'idi rẹ mulẹ laarọ oni, Fraide wi pe ọna lati ma jẹ ki arun naa ti ara oun kaakiri lo jẹ k'oun gbe igbesẹ yii, to si tun loun ko mọ bi oun ṣe kagbako arun naa.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe o digba t'oun ba ri i pe ara oun ti ya patapata, t'awọn oniṣegun oyinbo si f'idi rẹ mulẹ pe oun ti bori arun naa, bakan naa lo jẹ ko ye awọn eeyan pe arun naa ki i ṣe idajọ iku rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI