Ẹ TUN WO ỌMỌ NAIJIRIA T'AWỌN FBI N WA LORI ẸSUN JIBITI, WỌN LO ṢEE ṢE KO TI SAPAMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 20, 2020

Ẹ TUN WO ỌMỌ NAIJIRIA T'AWỌN FBI N WA LORI ẸSUN JIBITI, WỌN LO ṢEE ṢE KO TI SAPAMỌ

Ko si ibi ti fọto gendekunrin ti ẹ n wo yii, Abiọla Ayọrinde Kayọde ko tii tan de lorilẹ-edeagbaye pẹlu bi ileeṣẹ FBI to n gbogun ti iwa ọdaran ati jibiti ṣe kede rẹ sita gẹgẹ bi ọdaran.

Ẹsun kan ti wọn pe ni Business Email Compromise (BEC) ni wọn fi kan Kayọde, ti wọn si lo o ti lu awọn ileeṣẹ ti ko din ni aadọrin (70) lorilẹ-ede United States ni jibiti owo ti ko din ni miliọnu mẹfa dọla ($6,000,000).

Lara awọn ti wọn ni Kayọde jọ n ṣiṣẹ jibiti ori ayelujara ni Alex Afolabi Ogunshakin, Felix Osilama Okpoh, ati Nnamdi Orson Benson, ti wọn si ni wọn f'oju wọn ba ile-ẹjọ, iyẹn United States District Court, District of Nebraska, Omaha, Nebraska lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun to kọja.

Lati ọjọ kejilelogun oṣu kẹjọ ọdun naa la gbọ pe wọn ti n wa Kayọde, ti wọn ko si ti i ri titi d'asiko ti wọn fi gbe fọto rẹ sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI