KAṢAMU KÒ GBỌ́DỌ̀ MÁA FI ARA RẸ WE BAYỌ DAYỌ, ỌNA JIN SÌ ARA WỌN - ṢOWUNMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 11, 2020

KAṢAMU KÒ GBỌ́DỌ̀ MÁA FI ARA RẸ WE BAYỌ DAYỌ, ỌNA JIN SÌ ARA WỌN - ṢOWUNMI


Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowunmi tí Sẹnetọ Buruji Kaṣamu lamọran wí pé kò dẹkun láti máa bá alaga àná fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Onimọ-Ẹrọ Bayọ Dayọ takurọ-sọ. 

Ṣẹ́gun Ṣowunmi sọ pé àwọn méjèèjì kii ṣe ẹgbẹ́ rárá, ọjọ́ orí lè ju ara wọn lọ, ṣùgbọ́n ipò tí wọn di mú lórílẹ̀-èdè yìí ju ara wọn lọ.

Gbajumọ olóṣèlú náà tó jẹ́ agbẹnusọ fún Alaaji Atiku Abubakar tó díje dupo Ààrẹ lọ́dún tó kọjá lo sọ̀rọ̀ náà laipẹ yìí n'ilu Abẹ́òkúta lásìkò tó ń bá àwọn oniroyin sọ̀rọ̀.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ohun tí mo máa sọ ní pe òṣèlú gba awada pupọ. Ọ̀nà tí a sì ń gbà ṣe òṣèlú wá lórílẹ̀-èdè yìí kọjá nnkan ti èèyàn lè sọ fún ọmọ rẹ láti wàá darapọ mọ.

"Àwọn èèyàn lè má gba ọ̀rọ̀ ara wọn gbọ mọ, ṣùgbọ́n mi ò lérò wí pé ó yẹ kí àwọn tí wọn tí bá ara wọn ṣe fún ọdún mọ́kànlá, tí wọn tí bá ara wọn jẹ, tí wọn tí bá ara wọn mu, tí wọn tí jọ rẹrin, tí wọn tí jọ sunkún, tí wọn tí jọ pín àṣeyọrí àti ijakulẹ àti bẹẹbẹẹ lọ, tó wá jẹ́ pé ìgbà tó yẹ kí wọn gba ògo àti idupẹ ni nnkan wá dàrú fún wọn pátápátá. Mí ó lérò wí pé ó yẹ kí wọn wá máa gba irú àwọn nnkan ìtìjú àgbáyé báyìí láàyè.


"Lai máa wò gbogbo wàhálà táwọn èèyàn náà ń bá ara wọn fà, mo ti dakẹ pátápátá lórí ọ̀rọ̀ wọn, nítorí pé bí ẹ bá wo Bayọ Dayọ, ìyàlẹ́nu lọrọ rẹ ń jẹ. Bayọ Dayọ parí ìṣàkóso ọdún mẹ́jọ rẹ gẹ́gẹ́ bí alaga ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nipinlẹ Ogun, gbogbo àsìkò rẹ, wàhálà lo bá àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ náà n'ilu Abuja fà. 

"Bí wọn ṣe ń kúrò ní kọọtu kan ni wọn ń bọ sì kọọtu miran, bí wọn ṣe ń ná owó ni wọn ń ná ara wọn. Àti pé Buruji Kaṣamu ni igi lẹ́yìn ọgbà rẹ tó fi ń ṣe gbogbo nnkan tó ń ṣe yẹn.

"Nigba tó ti wàá parí sáà rẹ pátápátá, ó wàá pinu láti yí padà gẹ́gẹ́ bíi Saul tó di Paul nínú Bíbélì, ó ń wá ọ̀nà láti ronú pìwà dà. Ó pinu láti kúrò lẹ́yìn Kaṣamu lọ sí ọdọ àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ náà l'Abuja tàbí lọ́dọ̀ Ladi Adebutu. 

"Ohun tí mi ò bá lérò pé ó yẹ kó ṣe ni pé, ó yẹ kó rántí pé oríṣiríṣi àṣírí làwọn tí jọ pín papọ̀, fún ìdí èyí nítorí ara wọn, àwọn mọlẹbi wọn, àwọn èèyàn wọn, ìlú ti wọn ti jọ wá, ẹgbẹ́ tí wọn jọ ṣe, àwọn ìyàwó wọn, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti igbega ipinlẹ Ogun, kò yẹ kí wọn máa yẹyẹ ara wọn níta gbangba, kí wọn máa dojú tí ara wọn káàkiri. 

"Ó máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa, àwọn èèyàn kii gba ara wọn gbọ́ mọ tó bá yá, ọrẹ ń kọ ara wọn silẹ, ìgbéyàwó ń dàrú, àwọn èèyàn máa ń pinu láti yàgò fún ara wọn tó bá tó asiko kan, ṣùgbọ́n síbẹ̀, kò wá yẹ kí wọn máa bá ara wọn fà wàhálà tó ń ko ìtìjú ita gbangba bá wọn yìí. 

"Ní ti Sẹnetọ Buruji Kaṣamu táwọn èèyàn ń wo bíi pé òun ni lana, òun náà tún ní lónìí, ṣe ló yẹ kó rántí wí pé ọlọ́lájùlọ lo jẹ́ lórílẹ̀-èdè yìí, nítorí pé ó ti lọ silu Abuja láti lọ sìn àwọn aráàlú, ó sì padà lọdun 2019. Nkankan wá ti wọn n pe ni 'Ipò àwọn Aláṣẹyọrí' {Role of Honour} làwọn orilẹ-ede. 

"Nígbà tí oniṣẹ ìwádìí bá lọ sí orilẹ-ede kan láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn Aláṣẹyọrí, wọn a bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn Ààrẹ, Aṣofin, Aṣoju-ṣofin, àti bẹẹbẹẹ lọ. Orúkọ Kaṣamu máa wà nínú orúkọ àwọn aṣofin ana. Ó yẹ kó máa tó ara rẹ sípò àgbà, ipò ọlọ́lá ni, bẹẹ lo sì yẹ kó máa ronú nípa àwọn igbesẹ tó bá fẹẹ gbé àti ọ̀rọ̀ tó bá fẹẹ sọ, àti bí yóò ṣe máa jijakadi


"Orúkọ rẹ yẹ kó jẹ́ nnkan ajọgunba rere fáwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ lọ́jọ́ iwájú. Kini wọn ń wá káàkiri ojú àwọn ìwé ìròyìn àti orí ayélujára?

"Mo fẹẹ bẹ Kaṣamu pé kò gbé ara rẹ sókè dáadáa kò si pàṣẹ wí pé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ orí ayélujára àti ìwé ìròyìn gbọdọ̀ dakẹ jẹ́, nítorí pé ó lè má mọ irú àkóbá ńlá tí àwọn nǹkan náà ń ṣe fún orúkọ rẹ. 

"Bayọ Dayọ kii ṣe Aṣofin, kò ṣe aṣofin rí. Kaṣamu ni aṣofin to sì jẹ ẹgbẹ́ àwọn aṣofin bíi Okunrounmu, Kàkà, David Mark, Tinubu àti bẹẹbẹẹ lọ, kò lè máa fi ara rẹ wé Dayọ tí kò di ipo ńlá mú lorilẹ-ede yìí rí ju alaga ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọn kò mọ lọ." 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI