KAYEEFI ŃLÁ! OLUDASILẸ ṢỌỌṢI FIPÁ BA ỌMỌ ỌDÚN MOKANDINLOGUN LAṢEPỌ NÍNÚ ṢỌỌṢI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 10, 2020

KAYEEFI ŃLÁ! OLUDASILẸ ṢỌỌṢI FIPÁ BA ỌMỌ ỌDÚN MOKANDINLOGUN LAṢEPỌ NÍNÚ ṢỌỌṢI


Oludasilẹ Ṣọọṣi Victory Revival Fasting and Prayer Ministry to wá n'ilu Warri, ipinlẹ Delta, Biṣọọbu Elijah Orhonigbe lo tí fojú bá ile-ẹjọ lọ́jọ́ Ajé, Mọnde ijẹta yìí lórí ẹ̀sùn wí pé ó fipá bá ọmọdébìnrin kan laṣepọ nínú ṣọọṣi, lẹ́yìn tó rọọ l'ọti yo tán. 

Ogunjọ oṣù karùn-ún là gbọ pé Elijah fipá bá ọmọ laṣepọ, lẹ́yìn tó tán Màmá ọmọ náà pé òun fẹẹ ṣe itusilẹ fún ọmọ rẹ, àti pé inú ṣọọṣi ni itusilẹ náà yóò ti waye. 

Wọn ní òróró ìyanu ní Elijah fi ọtí sì, tó sì fún ọmọ náà mú, èyí ni wón loo jẹ́ kó rí ààyè láti bá ọmọ náà sún níwájú pẹpẹ ṣọọṣi ẹ. 

AWIKONKO gbọ pé ìran burúkú kan ni Elijah lòun rí sì ọmọ yìí, wí pé àwọn ọmọ Yahoo bàa laṣepọ, wọn si fi ṣoogun owó, tó sì loo gbọdọ tètè wàá ṣe itusilẹ tipátipá kò too pẹ ju. 

Bó ṣe ṣetan ni wọn lójú ọmọ náà là, tó sì pariwo síta, nígbà tó sọ̀rọ̀ náà fún màmá rẹ ni wọn gba teṣan ọlọ́pàá lọ láti fi tó wọn létí, látìgbà náà là ní wọn ní Elijah tí na pápá bora, ṣùgbọ́n tí wọn padà ríi mú lọ́jọ́ karùn-ún oṣù yìí. 

Elijah nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sọ pé wọn purọ mọ òun ni nítorí pé lóòótọ́ lòun gbàdúrà itusilẹ fún ọmọ yìí, ṣùgbọ́n tó loo yà òun lẹ́nu nígbà tí wọn fẹsun ifipabanilopọ kan òun.

Ó níwájú àwọn mẹ́ta lòun tí gbàdúrà náà lọ́jọ́ náà táwọn èèyàn sì lè jẹri sii wí pé òun kò bá ọmọ náà laṣepọ.

Kọmiṣanna ipinlẹ náà, Mohammed Hafiz Inuwa kanminu lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó sì ni igbesẹ tí bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ òfin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI