L'ọjọ Ẹti, iyẹn Fraide ana ni ijọba ibilẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRazaq bẹrẹ atunṣe lori afara odo-Agba, iyen Agba-Dam n'ipinlẹ naa.
Amugbalẹgbẹ Gomina lori iroyin ayelujara, Ọgbẹni Ọlayinka Fafoluyi lo f'idi ẹ mulẹ lori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ.
Fafoluyi sọ pe bi ijọba ṣe n ṣe atunṣe lori awọn afara odo to ti bajẹ kaakiri ipinlẹ naa, lo mu k'ijọba tun bẹrẹ atunṣe lori afara odo Agba naa fun irọrun araalu.
Laipẹ yii ni afara odo Oko-Erin ja lulẹ, to si pa awọn mẹta loju ẹsẹ, eyi tun pẹlu idi t'ijọba fi bẹrẹ atunṣe awọn afara yooku lati ma baa jẹ k'awọn araalu tun kagbako iku ojiji.
No comments:
Post a Comment