NPOWER! ỌNA LATI FORÚKỌ SÍLẸ̀ RE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 27, 2020

NPOWER! ỌNA LATI FORÚKỌ SÍLẸ̀ RE E


Awọn alakoso N-Power tii se eto igbanisiṣẹ fawọn ọdọ lórílẹ̀-èdè Naijiria ti fi ikilọ sita pe ọfẹ ni eto igbanisiṣẹ naa.

Ikilọ yi ko ṣẹyin bi awọn eeyan kan ti ṣe n gbiyanju lati forukọ silẹ loju opo N-Power saaju ki wọn to ṣii laago mejila ku iṣẹju mẹẹdogun alẹ ọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹfa.

Gẹgẹ bi iroyin lati oju opo naa ti ṣe sọ, iforukọsilẹ to ba waye ṣáájú asiko yi jẹ otubantẹ ni yoo ja si fẹni ba ṣe iru rẹ.

Ijọba apapọ Naijiria lo ṣe agbekalẹ eto iranwọ iṣẹ́ N-Power labẹ ileeṣẹ to n rí si idagbasoke awujọ ni Naijiria fawọn ọdọ ti ko ba niṣẹ lọwọ.


Bi o ti se le forukọsilẹ kopa ninu N-Power 2020 ree

Labẹ eto igbanisisẹ N-Power ipele kẹta to n waye loṣu kẹfa, awọn to ba fẹ jẹ anfaani yi yoo lọ si oju opo ayelujara www.npower.fmhds.gov.ng lati forukọ silẹ.

Sugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa lo le kopa.

Lati jẹ anfaani yi, eeyan gbọdọ jẹ ẹni ọdun mejidinlogun si marundinlogoji.

Wo awọn iwe to gbọdọ ni ko to le forukọ silẹ:

•Nọmba idanimọ ile ifowopamọ, ìyẹn BVN

•Aworan pelebe

•Oju opo ikansiraẹni e-mail ati nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn le fi pe ọ si

•Iwe ẹri ikẹkọọ gboye fasiti ati sabuke agunbanirọ NYSC

Kete ti o ba ti de oju opo N-Power, awọn ohun to yẹ ko se ree:

•Fi e-mail rẹ tabi nọmba foonu rẹ si oju aye ti wọn pese.

•Ṣíṣe bẹẹ yoo mu ki o gbe ọ lọ si ibi ti o ti jẹri pe lóòótọ́ iwọ lo ni e-mail

•Bi o ba ṣe eyi tan, o ni lati kọ nọmba idanimọ ile ifowopamọ BVN rẹ ati ọjọ ibi rẹ (dd/mm/yr)

•Abala iroyin nipa rẹ ati oju opo ikansiraẹni: kọ orukọ baba rẹ, orukọ rẹ bo ti se wa lori nọmba BVN rẹ

•Abala iwe ẹri ẹkọ ati eto miran: labala yi, o le kọ ọ sibẹ boya o kawe gboye tabi o lọ si ile ẹkọ rara.Gbogbo eeyan ni eto N-Power wa fun

•Abala Eto N-Tech ati N- Health wa fawọn to kẹkọ gboye ile ẹkọ giga nikan.

Etò NPower jẹ́ ọ̀nà tí ìjọba Nàìjíríà fi ń pèsè iṣẹ́ àti ìgúnpá fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe.

Awọn to kawe gboye fasiti, ile ẹkọ gbogbonise HND tabi OND lẹka eto ẹkọ imọ ilera, Microbiology, Psychology, Midwifery Public Health tabi eto ẹkọ miran lẹka sayẹnsi lo le kopa nibẹ.

•Awọn to n waṣẹ yi ni lati fi ẹda iwe ẹri ikẹkọgboye fasiti wọn ati iwe ẹri agunbanirọ NYSC sọwọ loju opo naa .

•Oju opo Iṣẹ́ ati awọn iroyin miran:

Awọn to n wa'ṣẹ ni lati dahun awọn ibeere kan ti wọn yoo si fi ẹda kaadi idanimọ wọn sọwọ. Iwe ẹri ti ijọba fontẹ lu niwọn yi:

•Iwe irina pasipọti

•Kaadi idanimọ ti ajọ NIMC n fun awọn ara ilu

•Iwe asẹ iwakọ ni Naijiria

•Kaadi idibo ọlọjọ pipẹ,PVC

•Ipele ayẹwo fini fini ka to pari:

•Nibi ni waa ti yẹ gbogbo nkan to kọ daada ti o si fi sọwọ si oju opo naa

•Bi o ba ti fi sọwọ si oju opo naa tan, wọn yoo fi nọmba idanimọ kan ransẹ si ọ,kọ silẹ ki o fi pamọ daada.


Iru awọn eeyan ti N-Power 2020 n wa?

Gẹgẹ bi awọn alasẹ ti se sọ, eto igbanisisẹ yi yoo gba eeyan ẹgbẹrun lọna irinwo sisẹ lẹka orisirisi bi isẹ ọgbin, ilera, eto ẹkọ, ile kikọ, isẹ ọna ati imọ ẹrọ tẹkinọlọji.

Ọdun 2016 ni ijọba bẹrẹ eto naa ti eeyan to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta si ti jẹ anfaani nibẹ.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI