ÀWỌN ARÁÀLÚ TUN F'ẸHONU HAN N'IBADAN L'ORI IPANIYAN OJOOJUMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 27, 2020

ÀWỌN ARÁÀLÚ TUN F'ẸHONU HAN N'IBADAN L'ORI IPANIYAN OJOOJUMỌ


Awọn ara adugbo Ṣáṣá, ìjọba ìbílẹ̀ Akinyele ni ilu Ibadan ti ké gbàjarè s'ijọba lati pese eto aabo tó péye fun wọn lẹyin ti awọn kan tun ṣá obinrin kan ni ada pa ni aarọ kutu Ọjọru, Wẹside to kọjá lọ. 

Awọn ara adugbọ to sọrọ ni arabinrin Olufisayo Fagbemi ji laarọ kutu bi aagọ marun un lati fọ aṣọ ni iwaju ile, ki wọn to ba a ninu agbara ẹjẹ.

Lẹyin ti wọn sa a ni ada ni iwaju ori ni Ọjọru.
 
Awọn ara adugbo wi pe ẹni karun un ni yii laarin oṣu kan ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo lagbegbe yii.

Bẹẹ ni wọn kesi ijọba lati ṣeranwọ fun wọn, ki oju awọn aṣebi yii tete han sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI