O MA ṢE O! IKU AJIMỌBU DI IBẸREU NLA F'AWỌN ALAGBARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 26, 2020

O MA ṢE O! IKU AJIMỌBU DI IBẸREU NLA F'AWỌN ALAGBARA

BỌSUN ỌLANIYI, ABẸOKUTA - Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe Gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ti tẹri gbaṣọ, o si ti lọ s'ibi t'awọn agbaagba, iyẹn awọn arugbo ti lọ.

Ẹni aadọrin (70) ọdun ni Abiọla Ajimọbi ko too dagbere f'aye ni ọsibitu First Cardiologist and Cardiovascular Consultants to wa n'ilu Eko.

AWIKONKO gbọ pe aisan to ni i ṣe pe arun koronafairọọsi lo ṣeku pa Ajimọbi, yatọ si pe o ni aisan itọ-ṣuga lara tẹlẹ.

Ọjọ keji oṣu yii ni Ajimọbi ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi alaga fidihẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹ-ede Naijiria laipẹ yii, ṣugbọn ti ko de ori ipo naa ti wa l'ọsbitu naa.

Wọn ni awọn ayẹwo Covid-19 ti wọn ṣe fun Ajimọbi ni ko so eso rere, ṣugbọn ti aisan rẹ tun n peleke si i, eyi lo mu ko bẹbẹ pe ki wọn f'oun si yara adagbe lati le gba itọju gidi, ṣugbọn to pada ku.

'Ko le jẹ bẹẹ, ko le ri bẹẹ' lọrọ iyalẹnu to n ṣi n ti ẹnu ọpọ awọn eeyan jade wi pe Abiọla Ajimọbi ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, to si n ṣe pupọ ni kayeefi.

Gbogbo awọn alagbara lorilẹ-ede Naijiria ni wọn ti wa ninu ibẹrubojo bayii nitori iku Ajimọbi, ti wọn si ti n n'igbagbọ gidigidi bayii wi pe arun koronafairọọsi wa nita, ko si gboogun kankan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI