Nnkan ko dẹrun rara fun pupọ awọn araalu Abẹokuta ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun loni ọjọ Abamẹta, Saide, ọjọ kẹrin oṣu keje lori ojo arọọrọra to rọ fun bi wakati mọkandinlogun, ti ko si ti i da lasiko ta a kọ iroyin yii tan laago mẹsan-an ku iṣẹju mẹẹdogun.
Lati nnkan bi aago kan oru la gbọ pe ojo naa ti bẹrẹ loni pẹrẹu, to si rọ tilẹ fi ṣu.
Ọpọ ile ni agbara ojo wọ, to si ba obitibiti dukia olowo iyebiye jẹ kaakiri Abẹokuta, to fi mọ fẹnsi ayika ile ikawe Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọbasanjọ Presidential Library to wa ni Oke-Mọsan.
Lara awọn ibi ti agbara ojo naa ti ṣọṣẹ ni Isalẹ-Igbein, Kutọ, Ẹnu-Gada si Lafẹnwa, Amọlaṣọ, Ijeun-Titun, Agọ-Ijẹṣa, Abiọla-way, Isalẹ Abẹtu, Ṣokori, Igbore to fi mọ Isalẹ-Ake.
Yatọ si ọpọ dukia to ṣofo danu, ko din ni mọto mẹtadinlọgbọn ni omi gbe, ti agbara si wọnu awọn mi in ti wọn paaki sinu ile ati opopona, bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ wi pe awọn eeyan padanu ẹmi wọn.
Diẹ ree lara awọn ibi ti agbara ojo naa ti ṣọṣẹ:
No comments:
Post a Comment