Gbajugbaja egúngún ká máa ní ìlú Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun lo tí k'àgbákò àwọn ọlọ́pàá báyìí, lórí bo se dunkooko mọ àwọn aráàlú.
Ibẹrubojo là gbọ pé ó dá sí ọkàn àwọn aráàlú lásìkò tó jáde síta, tó mú sì káwọn èèyàn máa sá kijokijo.
Ọkàn lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá lójijì, ìyẹn Ismaila Mukaila là gbọ pé ó fara kaaṣa, tó sì farapa yannayanna.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sóju wọ́n sàlàyé pé, àwọn tó n tẹ̀lé eégún náà kó onírúurú ǹkan ìjà tó léwu lọ́wọ́, ìdí nìyìí tí wọ́n fi mú ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ ọlọ́pàá.
Lẹ́yìn èyí ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá dá àwọn ẹsọ́ aláàbò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n nígbà ti wọ́n dé bẹ̀, àwon ọmọ lẹ́yìn eégún kọjú ìjà sí àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú ìbọ̀n.
Ọwọ́ sìnkún ọlọ́pàá ba èniyàn mẹ́fà nínú wọ́n, to fi mọ eégún ọ̀ún fúnra rẹ̀.
Kọ́mísọ́nà ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Ọṣun, Undie Adie fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, nípa bí wọ́n ṣe mú eégún àti àwọn ìsọngbè rẹ̀.
Àwọn nǹkan ti wọ́n gbà lọ́wọ́ wọ́n ni òògùn, ìbọ́n ìgbàlodé kan, ìbọ̀n ọdẹ kan, àdá méjì, ààké àti gángan mẹ́rin.
Ọ̀gá ọlọ́pàá náà sàlàyé pé, àti eégún àti àwọn tókù rẹ̀ kò ni lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n.
No comments:
Post a Comment