GOMINA ABDULRAZAQ BURA F'AWỌN AKỌWE AGBA MẸRINDINLOGUN LỌJỌ KAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 4, 2020

GOMINA ABDULRAZAQ BURA F'AWỌN AKỌWE AGBA MẸRINDINLOGUN LỌJỌ KAN ṢOṢO


L'oni ọjọ Satide, Abamẹta ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara bura f'awọn akọwe agba mẹrindinlogun tuntun ti yoo ba a ṣiṣẹ pọ ninu ijọba rẹ. 

Akọkọ iru ẹ ree latigba ti Gomina AbdulRazaq ti gba ijọba lati ọdun kan le diẹ sẹyin. Nibẹ lo si ti gb'awọn nimọran lati ṣiṣẹ papọ gẹgẹ ọrẹ, mọlẹbi ati ikọ nipa ikora-ẹni-nijanu fun igbelarugẹ ipinlẹ naa ati ijọba toootọ.

Bakan naa lo tun fi n da wọn loju pe ijọba ko ni fi ọwọ yẹpẹrẹ mu oṣiṣẹ ijọba to wa lọwọ si iwa ajẹbanu tabi ṣe kumọkumọ, to si l'awọn eeyan yii fẹẹ ṣiṣẹ papọ lasiko ti wọn fẹ maa mọ riri owo ipinlẹ naa ninu ijọba rẹ. 



Abdulrazaq sọ pe ajakalẹ arun koronafairọọsi to wọle wa ti jẹ ki nnkan le koko ninu ijọba, eyi to loo ti din owo to n wọle ku, to si ni anfaani lati ronu nipa ọna mi in lo tun jẹ fun wọn lasiko ajakalẹ arun naa.

Ninu ọrọ tiẹ, olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Oluwọle Dupẹ Susan gbe oriyin fun Gomina AbdulRazaq fun bo ṣe n gbaruku ti awọn oṣiṣẹ ijoba latigba to ti gba ipo naa, to si ni iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ tipẹ.

O wa gba awọn eeyan naa lati tubọ ṣiṣẹ takuntakun lati le gba oriyin lasiko to yẹ, paapaa ko to o di pe wọn fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba.

Awọn ti wọn bura fun naa ni: Adenikẹ Ibrahim Afusat (Ministry of Social Development); Shuaib Boni Ahmed (Establishment); Goshiya Jiya (Civil Service Commission); Musa Idris (Justice); Maryam Nurudeen Mohammed (Agriculture); Halimat Adukẹ Eletu (Enterprise); ati Ọlayiwọla Ayinla Abubakar (Health).

Awọn yooku ni: Grillo (Cabinet, Political and Special Services); Alabẹrẹ Razaq Babatunde (Local Government); Rabiat Abdulrahman Mopelọla (Communication); Ọkanlawọn Musa Ọlanrewaju (Water Resources); Yusuf Bọlakalẹ Abdullahi (Special Duties); Iyabọ Banirẹ Funkẹ (Sports); Bamigbe Rotimi Williams (Energy); Adeọṣun Mary Kẹmi (Education); ati Olorukooba Isiaka Yinka (Works).




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI