GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE PAṢIPAARỌ ÀWỌN KỌMIṢANNA RẸ̀, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN GBÉ OṢUBA KARE FÚN ILEEṢẸ BUA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 4, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE PAṢIPAARỌ ÀWỌN KỌMIṢANNA RẸ̀, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN GBÉ OṢUBA KARE FÚN ILEEṢẸ BUA

Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti kede sita wi pe ijọba oun ti ṣe paṣipaarọ ipo f'awọn kọmiṣanna to n ba a ṣiṣẹ, fun idagbasoke eto IṢẸYA to n lọ lọwọ n'ipinlẹ naa.

Ọjọ Ẹti, Fraide ana ni Ọgbẹni Rafiu Ajakaye fi iroyin naa ṣọwọ s'awọn oniroyin, eyi ti AWIKONKO naa wa lara wọn.

Yatọ si eyi, Gomina AbdulRazaq tun gbe oṣuba kare fun awọn alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ BUA lori bi wọn ṣe fi awọn mọto iṣẹlẹ pajawiri f'awọn alaisan (Ambulanse) mẹta ọtọọtọ ta wọn lọrẹ.

Awọn kọmiṣanna marun-un ti wọn ṣe paṣipaarọ ipo fun ni kọmiṣanna fun eto ikansira-ẹni (Communication), Ọlanrewaju Murtala ti wọn gbe lọ si ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko (Ministry of Agriculture and Rural Development); ti wọn si gbe kọmiṣanna to wa nibẹ tẹlẹ, Harriet Adenikẹ Afọlabi Oshatimẹhin lọ si ileeṣẹ ikansira-ẹni. 

Kọmiṣanna fun eto ayika, Arch. Aliyu Mohammed Saifudeen ni wọn gbe lọ si ileeṣẹ to n ri sọrọ oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe; Kọmiṣanna fun eto oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe, Hajia Aisha Ahman-Pategi ni wọn ti gbe lọ si ileeṣẹ to n ri akanṣẹ iṣẹ (Special Duties); n'igba ti wọn gbe Kọmiṣanna to wa ni ileeṣẹ to n ri si akanṣẹ iṣẹ, Funkẹ Juliana Oyedun lọ si ileeṣẹ to n ri si eto ayika ati agbegbe (Environment).

N'igba to n gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ BUA, Gomina AbdulRazaq sọ pe inu oun dun si ileeṣẹ naa, nitori pe wọn ti ohun to jọju pataki lati ran ipinlẹ naa lọwọ.

Oṣu mẹta sẹyin ni ileeṣẹ naa fi ọgọrun miliọnu naira ta ijọba ipinlẹ naa lọrẹ lati fi gbogun ti itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19 to n ja kaakiri agbaye.

Nibẹ ni Gomina tun ti ṣalaye bi wọn ṣe na biliọnu lọna igba ati mẹtalelogoji (N243b) naira t'awọn ileeṣẹ aladani at'awọn oluranlọwọ fi ta wọn lọrẹ lati gbogun ti arun koronafairọọsi laaarin ọjọ kẹtadinlọgbọ oṣu kẹta si asiko yii.

Akọwe iroyin Gomina, Rafiu Ajakaye, ẹni to tun jẹ alaga olupolongo fun didẹkun itankalẹ arun naa sọ pe owo to le diẹ ni biliọnu kan aabo (N1,569,107,944.70) naira lawọn ti na laaarin ọjọ kinni oṣu kẹrin si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI