BABA TO N BA ỌMỌ BIBI INU RẸ LAṢEPỌ DERO ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 4, 2020

BABA TO N BA ỌMỌ BIBI INU RẸ LAṢEPỌ DERO ATIMỌLE


Ọgba ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ni baba ti ẹ n wo yii wa lasiko ta a kọ iroyin yii tan, nibi to ti n ṣalaye ara rẹ lori idi pataki to fi n ko ibasun fun ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun karakara.

A gbọ pe awọn ọlọpaa ninu ipolongo wọn lodi si iwa ifipabanilopọ laarin ọsẹ yii l'ọwọ palaba baba naa, Matthew Joseph, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ti tu.

Ki i ṣe pe Matthew n fipa ba ọmọ rẹ laṣepọ nikan, ṣe ni wọn lo o tun fun un loyun pẹluu. Latigba ti wọn ni Mathew ti kọ iyawo ẹ, to jẹ iya ọmọ yii silẹ l'odun to kọja ni wọn lo o ti ri i gẹgẹ bi anfaani lati maa ba ọmọ rẹ yii sun.

N'igba to n fi idi iroyin naa mulẹ fun awọn oniroyin, alukoro f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Suleiman Nguroje sọ pe agbegbe kan n'ijọba ibilẹ Yola South ni Matthew n gbe pẹlu ọmọ rẹ.

Suleiman lo si jẹ ka mọ pe oyun to wa ninu ọmọ naa ti pe oṣu mẹta gbako bayii, to si lo o ti wa l'ọsibitu to ti n gba itọju. Bẹẹ lo sọ pe o di dandan ki Matthew f'oju ba ile-ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI