KORONAFAIRỌỌSI! IRỌ NLA NI PE MILIỌNU MẸTADINLOGUN NAIRA N'IJỌBA KWARA N NA LOJUMỌ - IJỌBA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 4, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! IRỌ NLA NI PE MILIỌNU MẸTADINLOGUN NAIRA N'IJỌBA KWARA N NA LOJUMỌ - IJỌBA PARIWO SITA

Amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin ayelujara fun ijọba ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọlayinka Michael Fafoluyi ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin kan to jade sita laipẹ yii pe miliọnu mẹtadinlogun naira n'ijọba ipinlẹ naa n na lojumọ lati dẹkun itankalẹ arun koronafairọọsi.

O ni ayederu iroyin pọmbele n'iroyin naa jẹ, ati pe irọ nla to jinna si otitọ ni ẹni to ṣagbatẹru iroyin naa n pa fun gbogbo agbaye, bẹẹ lo tun ni iroyin ẹlẹjẹ paraku ni.

Laipẹ yii n'ijọba Kwara gbe atẹjade sita wi pe owo ti ko din ni ọgọrun kan ataabọ miliọnu (1.5m) naira lohun ti na lojuna lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19.

Bi atẹjade naa ṣe jade sita ni akọroyin naa kọ ọ sori ikanni ayelujara wi pe miliọnu mẹtadinlogun naira n'ijọba Gomina Abdulrahman Abdulrazaq n na lojumọ lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19, ti iroyin naa si sọ pe iwa kikun lohun ṣe nipa ẹ.
Atẹjade naa ti Ọgbẹni Rafiu Ajakaye to jẹ alaga eto ipolongo didẹkun itankalẹ ajakalẹ arun naa fi sita lo ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe na owo naa laaarin ọjọ kinni oṣu kẹrin si ọjọ kọkandilọgbọn oṣu kẹfa.

Ni kete ti atejade yii jade sita ni oniroyin ayelujara naa sare kọ ọ sita wi pe miliọnu mẹtadinlogun naira n'ijọba l'ohun n na lojumọ, eyi ti wọn ni ko ri bẹẹ rara, ati pe iroyin ẹlẹjẹ lati ba orukọ ijọba jẹ ni.

N'igba to n tako iroyin ẹlẹjẹ naa, Ọgbẹni Fafoluyi sọ pe ṣe ni akọroyin naa kan fẹẹ tabuku ba ijọba nitori pe ki i ṣe nnkan ti ijọba gbe jade ni onioryin naa kọ sita.

Fafoluyi ni bi akọroyin naa bi akọroyin naa ba ṣe iwadii rẹ ni kikun, to si tẹle atẹjade bi wọn ṣe na owo naa, yoo mọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ti ko ṣe e gbọ seti ni akọroyin naa kọ.

O ni lorilẹ-ede Naijiria lonii, ipinlẹ Kwara pẹlu awọn ipinlẹ mẹrin ti wọn ki i na owo baṣubaṣu, paapaa lasiko itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19.

O ni o ṣeni laaanu wi pe pẹlu bi ijọba ṣe ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe na owo to wọle fun ipolongo ọna lati dẹkun arun naa to, ṣe ni akọroyin naa tun lọ kọ ikọkukọ sori ikanni rẹ, to si ni ko bojumu to.

Fafoluyi beere ọna ti akọroyin naa fi ṣiro owo naa to fi ku si miliọnu mẹtadinlogun lojumọ laaarin ọjọ kinni oṣu kẹrin si ọjọ kokandilọgbọn oṣu kẹfa.

O ni ijọba to wa nita yii faaye silẹ f'awọn eeyan lati sọ erongba wọn lọna to ba yẹ, ṣugbọn ko ni i gba iroyin ẹlẹjẹ to le tabuku ba ijọba laaye.

Ọkunrin naa wa a gba ẹgbẹ akọroyin lamọran wi pe ki wọn maa ri i daju pe wọn n ṣayẹwo f'awọn eeyan ko to di pe wọn gba wọn sinu ẹgbẹ akọroyin, nitori pe awọn eeyan buruku bayii ni wọn n tabuku ba iṣẹ naa.

Bẹẹ lo tun gba awọn araalu lamọran wi pe ki wọn yẹra f'awọn oniroyin to jẹ pe ọna atijẹ ni wọn n wa nipa kikọ iroyin ẹlẹjẹ t'awọn kan n san owo ẹ fun wọn lati ba orukọ olorukọ jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI