AJAYI, IGBAKEJI GÓMÌNÀ TÚN GBÉ OGUN NLA DIDE SÌ AKEREDOLU L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 4, 2020

AJAYI, IGBAKEJI GÓMÌNÀ TÚN GBÉ OGUN NLA DIDE SÌ AKEREDOLU L'ONDO


Ọna mi in ni wàhálà tó wà láàárín Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu t'ipinlẹ Òndó àti igbá-kejì rẹ, Agboọla Àjàyí, tó sì ń yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu.

Lọ́jọ́ Fraide àná ni Àjàyí sọ fún Akeredolu wí pé kò gbé ìjọba ipinlẹ náà silẹ foun nítorí ìlera ara rẹ kò gbé iṣejọba mọ.

Ọgbọn ọjọ́ oṣù tó kọjá yìí ni Akeredolu lọ fún isera lẹ́yìn tí ayẹwo fìdí rẹ múlẹ̀ pé ó ti kó ajakalẹ àrùn aṣekupani tí COVID-19.

Ajayi ninu ọrọ rẹ sọ pé òun fún Akeredolu ni ọjọ́ mọkanlelogun láti gbé ìjọba ipinlẹ náà silẹ foun ni ìbámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Akeredolu ṣáájú àsìkò yìí tí ṣàpèjúwe igbá-kejì rẹ, Àjàyí gẹ́gẹ́ bí idunkooko nínú ìjọba, àti pé Ajayi kò sì nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC mọ, nítorí náà ni òun kò ṣe lè gbé ìjọba silẹ fún un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI