NỌỌSI ṢA IYAWO AT'AWỌN ỌMỌ Ẹ PA L'ỌṢUN, LO BA L'AWỌN ADIGUNJALE NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 27, 2020

NỌỌSI ṢA IYAWO AT'AWỌN ỌMỌ Ẹ PA L'ỌṢUN, LO BA L'AWỌN ADIGUNJALE NI

Kayeefi nla lọrọ baale ile kan, Tunde Oyeniran to ṣa iyawo at'awọn ọmọ ẹ meji pa lale ọjọ Ẹti, Fraide to kọja yii ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan.

Nnkan bi aago mọkanla alẹ la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Inisa, ipinlẹ Ọṣun, n'igba ti wọn sọ pe Tunde ki ada mọlẹ, to si ṣa iyawo rẹ, Sarah at'awọn ọmọ meji ti wọn jọ bi.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le f'idi nnkan to ṣẹlẹ laaarin wọn mulẹ nipa idi ti Tunde fi gbe igbesẹ naa lasiko ta a kọ iroyin yii tan, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe ija ti maa n waye laaarin wọn lọpọ igba, t'awọn araadugbo si maa n ba wọn da si i.

Bi Tunde ṣe ṣa iyawo rẹ, Sarah at'awọn ọmọ meji yii pa tan, ni wọn lo o tun gun ara l'ọbẹ lọwọ, to si tun fi gun ara rẹ n'ikun, ko too di pe o pariwo sita f'awọn araale.

Irọ ti wọn ni Tunde pa f'awọn eeyan ni pe awọn adigunjale ni wọn wa ka awọn mọle, ti wọn si ṣa iyawo ati ọmọ oun pa, ti wọn si fẹẹ pa oun ko to o di pe oun pariwo sita, ti wọn si juba ehoro nígba ti wọn gbọ pe awọn eeyan ti n bọ.

Loju ẹsẹ ni wọn l'awọn eeyan ti ranṣẹ pe awọn ọlọpaa, ti wọn si gbe Tunde lọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju lọwọ. Ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti ri i pe Tunde lọ ṣiṣẹ buruku naa, ki i ṣe pe awọn adigunjale wa ka wọn mọle, idi ree ti wọn fi lọ duro tii lọsibitu lati le tubọ ṣewadi lẹnu ẹ daadaa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Arabinrin Yẹmisi Ọpalọla sọ pe ẹtanjẹ ni Tunde fẹẹ ṣe lai mọ pe aṣiri oun maa pada tu sita, to si l'awọn yoo f'ọwọ ofin mu Tunde lẹyin to ba tubọ gbadun l'ọsibitu daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI