O PARI! ÀṢÍRÍ AKỌWE AGBA TO LU JÌBÌTÌ N'ILỌRIN TU, BẸ́Ẹ̀ LỌ́WỌ́ PALABA ÀWỌN ỌGA AGBA L'ẸNU IṢẸ́ ÌJỌBA NÁÀ WỌ GAU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 1, 2020

O PARI! ÀṢÍRÍ AKỌWE AGBA TO LU JÌBÌTÌ N'ILỌRIN TU, BẸ́Ẹ̀ LỌ́WỌ́ PALABA ÀWỌN ỌGA AGBA L'ẸNU IṢẸ́ ÌJỌBA NÁÀ WỌ GAU


Bí ìwádìí ṣe ń tẹ síwájú lórí àwọn ayédèrú òṣìṣẹ́, èyí tí a mọ sì Ghost Workers nipinlẹ Kwara, àṣírí àwọn alẹnulọrọ lẹka eto iṣẹ ìjọba mi in tún ti tú síta báyìí. 

Ohun tó ń jẹ kayeefi ni bo ṣe jẹ́ pé àwọn ọga àgbà tí wọn ń wo gẹ́gẹ́ bí aṣiwaju ni aje ìwà ìbàjé jìbìtì náà ṣì mọ lórí. 

Akọ̀wé àgbà ní ẹka ileeṣẹ tó ń rí sì eto ẹ̀kọ́ ìyẹn SUBEB, Ọgbẹni Bayọ Audu Onimago; alakoso eto iṣuna ileeṣẹ náà, Husseni Ahmed; àwọn alakoso àpò-owó, Mujeeb Ibrahim àti Oyerinde Fatai àti òṣìṣẹ́ kan lẹka eto ẹ̀kọ́, ẹni tó tún jẹ́ alaga ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́, Toyin Saliu ni àṣírí wọn tún ti tú báyìí. 

Láti bí òsẹ mélòó kan sẹ́yìn báyìí ni àjọ tó ń gbógun ti ṣíṣe owó kumọkumọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, EFCC tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn ayédèrú òṣìṣẹ́ tí wọn ń gba owó oṣù nipinlẹ náà. 

Ìjọba ipinlẹ náà tí wá jawe gbele ẹ fúngbà díẹ̀, ìyẹn suspension fáwọn èèyàn náà, tó sì tún ti gbegile àwọn àpò ilé ifowopamọ wọn dìgbà tí ìwádìí yóò fi parí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI