O PARÍ! DOGARA ṢÀLÀYÉ ÌDÍ TÓ ṢE F'ẸGBẸ ÒṢÈLÚ PDP SILẸ LỌ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 26, 2020

O PARÍ! DOGARA ṢÀLÀYÉ ÌDÍ TÓ ṢE F'ẸGBẸ ÒṢÈLÚ PDP SILẸ LỌ APC


Abẹnugọn tẹ́lẹ̀ri fún ilé igbimọ aṣojú-ṣofin n'ilu Abuja, Yakubu Dogara tí ṣàlàyé ìdí pàtàkì tó ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party silẹ lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress. 

Ọjọ́ Ẹti, Fraide tó kọjá yìí ni Dogara ṣàlàyé ara rẹ, tó sì lòun kò lè bá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe mọ. 

Nínú lẹ́tà tó kọ sí alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni wọọdu C, ìjọba ìbílẹ̀ Bogoro lo tí sọ pé òun ti rí àwọn ìdí pàtàkì láti fi ẹgbẹ́ náà silẹ bọ sínú ẹgbẹ́ mi ín. 

Ó làwọn nnkan táwọn torí ẹ ja lọ́dún 2019 láti mú àyípadà bá ẹgbẹ́ náà nipinlẹ wọn ní kó sọ èso rere, tó sì tún ṣí wá nílẹ̀ títí di asiko yii.

Ninu lẹ́tà náà NI Dogara tún ti ń béèrè bí wọn ṣe ṣe owo ìjọba ìbílẹ̀ tó wọlé laarin oṣù karùn-ún ọdún tó kọjá títí di àsìkò yìí, bẹ́ẹ̀ lo tún béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè tí kò sẹni tó lè dáhùn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI