YAHAYA BELLO, GANDUJE ṢABẸWO IBANIKẸDUN SI GOMINA ABDULRAZAQ LORI IKU BABA RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 29, 2020

YAHAYA BELLO, GANDUJE ṢABẸWO IBANIKẸDUN SI GOMINA ABDULRAZAQ LORI IKU BABA RẸLatigba ti iroyin iku Alaaji AGF AbdulRazaq, to jẹ baba Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti jade sita l'awọn eeyan jankan-jankan ti n fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ s'awọn mọlẹbi.

Ana ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tuside ni Gomina ipinlẹ Kogi, Gomina Yahaya Bello naa tun ṣe abẹwo ibanikẹdun si Gomina AbdulRazaq lati ba a kẹdun iku baba wọn.

Nibi abẹwo naa ni Gomina Bello ti ṣapejuwe Oloogbe yii gẹgẹ bi ẹni to ṣiṣẹ takuntakun sin orilẹ-ede Naijiria, to si ni ipa to ko nibi ilọsiwaju orilẹ-ede yii, paapaa ipinlẹ Kwara ko le parẹ titi lai.

O ni lara awọn ipa rẹ naa ni bi wọn ṣe ipinlẹ Kwara tuntun silẹ, eyi ti wọn ti yọ ọpọ ilẹ fun ipinlẹ Kogi l'ọdun 1991.

Bello sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ f'oun nigba toun gbo iroyin nipa iku Baba naa, to si jẹ ipaya f'oun nitori pe ki i ṣe nnkan t'oun n reti.

O wa gbadura fun mọlẹbi AbdulRazaq wi pe ki Ọlọrun tu wọn ninu, ati pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.
 
Lara awọn to kọwọ rin pẹlu Gomina Bello ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC nípinlẹ Kwara, Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa; ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Raheem Ọlawuyi (Ajulọ-Opin), at'awọn mi in.

Yatọ si Gomina Bello at'awọn ikọ rẹ ti Gomina AbdulRazaq gba lalejo, awọn igbimọ oloye ati lọbalọba lagbegbe Barutẹn ati Edu naa ṣabẹwo ibanukẹdun.

Ṣaaju asiko yii ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti kọkọ ṣabẹwo ibanikẹdun rẹ l'ọjọ Aje, Mọnde ijẹta, nibi to ti ṣapejuwe baba naa gẹgẹ bi akikanju to fi apẹẹrẹ rere lelẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI