AṢILO OOGUN: AJỌ NDLEA ṢELERI IRANLỌWỌ FUN IJỌBA IPINLẸ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

AṢILO OOGUN: AJỌ NDLEA ṢELERI IRANLỌWỌ FUN IJỌBA IPINLẸ KWARA

Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun lorilẹ-ede Naijiria, National Drugs and Law Enforcement Agency, NDLEA ti sọ pe awọn ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara, k'awọn si le ran wọn lọwọ lati dẹkun iwa aṣilo oogun lawujọ.
 
Ọjọbọ, Tọside ana ni alakoso ajọ yii n'ipinlẹ naa, Ambrose Umar jẹ ki ọrọ yii di mimọ lasiko to n b'awọn akọroyin sọrọ lagbegbe Akerebiata to wa nilu Ilọrin, ipinlẹ naa.
 
Ajọ naa lohun yoo gbaruku ti bi aṣilo oogun yoo ṣe d'ohun igbagbe patapata lawujọ ipinlẹ naa.
 
Umar sọ pe ọna t'awọn le fi ri eyi ṣe ni wiwa ni ojufo ati ojulalakanfinṣọri lati mọ awọn agbegbe t'awọn eeyan ti n ṣi oogun lo, ki wọn si fi wọn jofin.
 
O ni aṣilo oogun yii jẹ ohun ipenija nla si eto aabo orilẹ-ede yii, t'awọn si gbọdọ dide lati ri ọwọ iwa ibajẹ naa bọlẹ ni waranṣeṣa.


 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI