300M LG FUND: IWADII TUNTUN JẸYỌ NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 21, 2020

300M LG FUND: IWADII TUNTUN JẸYỌ NI KWARABi igbimọ iwadii ti ijọba ipinlẹ Kwara gbe kalẹ lati tan imọlẹ si miliọnu lọna ọọdunrun (300m) naira ti wọn ni ijọba ipinlẹ naa n yọ ninu owo to n wọle f'awọn ijọba ibilẹ to wa nibẹ ṣe bẹrẹ l'Ọjọbọ, Tọside ana lawọn eeyan ti bẹrẹ si i jẹri loriṣiriṣi wi pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.
 
Igbimọ iwadii naa, eyi ti Adajọ-fẹyinti Mathew Adewara jẹ alaga rẹ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ si i pe awọn tọrọ kan lati wa a jẹri si ẹsun naa pẹlu ẹri aridaju.
 
Pupọ awọn to jade jẹri niwaju igbimọ naa ni wọn sọ pe owo t'awọn n gba pe geregere, ko si sẹni to yọ ninu owo awọn. Wọn ni owo oṣu nlọ dee de, bẹẹ ni ki si sẹni to ya wọn l'owo lati fi san owo oṣu wọn
 
Awọn alakoso eto iṣuna ata'awọn olusiro owo l'awọn ijọba ibilẹ mẹrindilogun yii, iyẹn Directors of Personnel Management (DPMs) bi i Asa, Ilorin East, Ilorin South, ati Ilorin West ni wọn jade sọrọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI