GOMINA UMAHI PAROKO IKU S'AWỌN ADARI NAIJIRIA TI WỌN N JALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 4, 2020

GOMINA UMAHI PAROKO IKU S'AWỌN ADARI NAIJIRIA TI WỌN N JALE

Gomina ipinlẹ Ebonyi Oloye David Umahi ti sọ pe b'awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ati iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC ati ICPC ṣe n mu awọn eeyan to, ko da awọn adari Naijiria duro lati maa jale.

O ni ile aye yii, afọwọba fi silẹ ni, to si jẹ pe iku nikan lo le gba gbogbo owo teeyan ba ji ko lọwọ ẹni, nitori naa lo ṣe n rawọ ẹbẹ s'awọn ọdọ kaakiri Naijiria lati ma ṣe ni ẹmi ole jija lọkan lati le tun orilẹ-ede yii ṣe.

Umahi, ẹni to tun jẹ alaga awọn Gomina fun ẹkun Guusu-Ila-Oorun orilẹ-ede yii lo sọrọ naa lasiko to n b'awọn oniroyin sọrọ nile ijọba ipinlẹ naa to wa nilu Abakaliki lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn gomina kan at'awọn agbaagba ilẹ Igbo kan.

Ninu ọrọ rẹ, Umahi sọ pe "Awọn eeyan ko nibẹru Ọlọrun lọkan rara, paapaa awọn ọmọ orilẹ-ede yii. Ki i ṣe nipa awọn EFCC, ICPC at'awọn mi in.  Ti a ba mọ pe ile aye yii, fun igba diẹ ni ati pe ijakadi la n wọ pẹlu iku bi a ba sun.

"Ọlọrun nikan lo maa n ji awọn aṣẹgun, to si yẹ ka bẹrẹ si i tun ero ọkan wa pa ati ẹri ọkan wa. Ko si iye awọn EFCC, ICPC to le awọn adari Naijiria lọwọ kọ lati ma ṣe jale. Ọlọrun ati ẹri ọkan nikan lo le ṣee.

"N'igba ti a ba dagba gẹgẹ bi adari, ki lo tun fẹẹ ri loju ọna ti o ti gba kọja tẹlẹ? Ki lo fẹ ki wọn fi mọ awọn ọmọ rẹ, bawo lo ṣe fẹ k'awọn eeyan bọwọ f'awọn ọmọ rẹ? Ṣe ki wọn bọwọ fun wọn nipa owo ti o ko jẹ ni tabi lori awọn ile nla-nla ti o kọ ni?

"O yẹ ka mọ pe gbogbo ọrọ aye yii, asan ati ofo ni wọn jẹ. O maa kuro lọwọ ẹnikan si bọ si ọwọ ẹlomiran ni. Awọn adari orilẹ-ede yii fẹẹ ji owo nitori k'awọn iran wọn ma ba a toṣi, ṣugbọn irọ lasan ni.

"Aisan kekere ti to lati gba gbogbo awọn nnkan ti o ji lọwọ rẹ. Mo n bẹ awọn ọdọ Naijiria lati tun ero ọkan wọn pa, ki wọn ṣe atunṣe. Wọn le fun wọn ni nnkan kekere lati ba ti ẹlomin jẹ. Bawo lo ṣe wa n ri lara wọn lati bi ọdun meji, mẹta si marun sẹyin. Ko le ṣiṣẹ.

"Lara awọn nnkan ti mo maa n sọ f'awọn ọmọ ipinlẹ Ebonyi ni pe mi o ni pin owo to yẹ fun idagbasoke ilu fun awọn alẹnulọrọ nílu. Ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fi ẹnu rẹ sọ, ko kan mi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI