IPINLẸ KWARA GBỌNA ARA YỌ PẸLU ILE ERE BỌỌLU TUNTUN, AKỌKỌ IRU Ẹ LORILẸ-EDE NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 28, 2020

IPINLẸ KWARA GBỌNA ARA YỌ PẸLU ILE ERE BỌỌLU TUNTUN, AKỌKỌ IRU Ẹ LORILẸ-EDE NAIJIRIA


Ijọba ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu ere bọọlu tuntun to jẹ akọkọ iru ẹ n'ilẹ Naijiria, eyi ti wọn fẹẹ fi bẹrẹ ere idaraya n'ipinlẹ naa pada.

Ana ti i ṣe Ọjọbọ, iyẹn Tọside ni Gomina bu ọwọ luu n'igba to n gba adari ere bọọlu lorilẹ-ede Naijiria, Amaju Pinnick lalejo n'ilu Ilọrin.
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ki ere ere idaraya pada lakọtun pẹlu ileri iranlọwọ to peye lat'ọdọ ijọba lati fi ṣe koriya f'awọn ọdọ to ni ẹbun ere idaraya loriṣiriṣi.
 
Gomina ni ọna ti awọn eeyan ko fi ni ko arun Covid-19 ni eto ere idaraya yoo gba bẹrẹ, to si ni awọn ere idaraya bi i Table Tennis, Badminton, Squash Racket, Golf, Cricket, Softball, Baseball, at'awọn mi in ni yoo bẹrẹ pada.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ile bọọlu yii la gbọ pe ẹgbẹ awọn agbabọọlu n'ipinlẹ ṣagbatẹru ẹ pẹlu iranlọwọ ijọba Gomina AbdulRazaq ati Amofin A.U Mustapha to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Confederation of African Football (CAF).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI