KORONAFAIRỌỌSI! IPINLẸ KWARA TUN GBA ỌGỌRUN MILIỌNU NAIRA LỌWỌ BANKI ÀGBÁYÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 9, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! IPINLẸ KWARA TUN GBA ỌGỌRUN MILIỌNU NAIRA LỌWỌ BANKI ÀGBÁYÉ


Bi Banki Agbaye ṣe n ṣe iranwọ fun awọn eeyan, paapaa awọn orilẹ-ede to fi mọ ipinlẹ lati fi dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun koronafairọọsi, ijọba ipinlẹ Kwara naa ti gba owo ti ko din ni ọgọrun miliọnu naira.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye fi ṣọwọ s'AWIKONKO lo ti fi ye wa pe lojuna lati ṣe iranwọ f'awọn ipinlẹ to n gbiyanju agbara wọn lati dẹkun itankalẹ Covid-19 naa, banki Agbaye pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ajakalẹ arun lorilẹ-ede Naijiria, NCDC ti fi ọgọrun miliọnu naira ta wọn lọrẹ.

Ajakaye sọ pe ki i ṣe pe Banki Agbaye pẹlu ajọ NCDC dee de fun awọn ni owo naa, bi ko ṣe pe awọn yege awón amuyẹ ati ilana ti wọn fi n pin owo naa, lo jẹ k'awọn naa lẹtọọ lati gba a.
Owo naa jẹ owo iranwọ ti Banki agbaye n pin lati fi ṣe iranwọ, eyi ti wọn pe ni World Bank-assisted Regional Disease Surveillance System Enhancement (REDISSE) project, ti ajọ NCDC si ṣagbatẹru ẹ.

Ipinlẹ Kwara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ diẹ ti wọn yege lati gba owo naa lẹyin ti wọn ri i awọn ọna ti wọn n gba na awọn owo wọn, paapaa lori ọrọ Covid-19.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI