Lonii ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara tun gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori ipese iṣẹ f'awọn ọdọ, at'awọn araalu, ti wọn si lo ti n mu idagbasoke ba eto ọrọ ajẹ ipinlẹ naa.
Níbi ipade kan ti ẹgbẹ naa ṣe lonii, ni wọn ti ṣalaye pe pẹlu ohun ti ileeṣẹ to n ṣe iwadii lori awọn nnkan to nii ṣe pẹlu araalu, iyẹn National Bureau of Statistics (NBC) ti fi han daju pe awọn ko ṣi ọkọ wọ, ati pe ọkọ AbdulRazaq t'awọn wa ninu ẹ yii yoo gbe awọn de ebute ayọ.
Siwaju si ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Alaaji Tajudeen Fọlaran Aro gbe sita lo ti ni gbogbo akitiyan gomina lo ti fi han daju bayii pe idagboske eto ọrọ aje wọn ko fẹẹ lẹlẹgbẹ mọ lasiko yii.
O ni lọjọ kẹrinla oṣu yii, iyẹn ọjọ Fraide to kọja yii ni ileeṣẹ NBS tun gbe esi iwadii wọn sita nipa ipese iṣẹ fun igbakeji ninu ọdun yii, to si fi han pe airiṣẹ ṣe ti dinku lawujọ, eyi ti ko ṣẹlẹ ri ninu itan lorilẹ-ede Naijiria.
No comments:
Post a Comment