SPARTAN: LẸYIN OṢU MẸJỌ, ALAAFIA WỌ IPINLẸ PẸLU IYALẸNU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 25, 2020

SPARTAN: LẸYIN OṢU MẸJỌ, ALAAFIA WỌ IPINLẸ PẸLU IYALẸNU


Bi wọn ba gun ẹṣin ninu awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun, paapaa awọn ara agbegbe Ipẹru, Ogere n'ijọba ibilẹ Ikẹnne, wọn ko ni i kọsẹ rara, ati pe oorun ayọ l'awọn eeyan yoo sun lalẹ oni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti rọwọ to ogbologbo apanijaye kan, Feyiṣọla Dosunmu t'ọpọ awọn eeyan tun mọ si Spartan, ẹni ti wọn lo n p'awọn eeyan nipakupa.

Awọn ti ko din ni mẹẹdogun la gbọ pe Spartan ti pa danu laaarin oṣu kinni si oṣu kẹjọ ọdun yii, lara wọn si ni igbakeji alaga agbegbe Oluwatẹdo, Alagba Ọladeji Ọlatunji ti wọn lo o ṣa pa.

Abimbọla Oyeyẹmi f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ wi pe ọwọ awọn ti tẹ ogbologbo ọdaran naa, to si ni ṣe ni wọn da ibọn bo o lasiko to fẹẹ na papa bora, lẹyin to b'awọn wọya ija.

Iyalẹnu ni bi wọn ṣe ri Spartan mu ṣi n jẹ fun pupọ awọn eeyan titi d'asiko ti a fi kọriyon yii tan o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI