Ẹ FURA O! AGBARA OJO NLA MBỌ NI KWARA - KỌMIṢANNA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 16, 2020

Ẹ FURA O! AGBARA OJO NLA MBỌ NI KWARA - KỌMIṢANNA PARIWO SITA

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ke gbajare s'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lati maa mura silẹ fun agbara ojo nla to n bọ lọna, eyi to ṣee ṣe ko ṣọṣẹ f'awọn eeyan lai lero.
 
Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati agbegbe,Arabinrin Funkẹ Julianah Oyedun lo sọrọ naa sita laipẹ yii wi pe k'awọn araalu, paapaa awọn to n gbe lagbegbe odo wa ni imurasilẹ fun agbara ojo nla naa, to si ni ki wọn tete wa ọna lati ko awọn ẹru wọn kuro nitosi odo ki asiko naa too de.
 
Arabinrin Funke Julianah Oyedun ni ọrọ oun ko ṣẹyin ọjọ iwaju t'awọn onimọ ati ọjọgbọn lẹka eto ayika, iyẹn Nigerian Meteorological Agency (NIMET) ti sọ wi pe ipinlẹ Kwara wa lara awọn ipinlẹ ti agbara ojo nla yoo da laamu pupọ, to si n gba wọn lamọran lati tete wa nnkan ṣe si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI